Ẹyọ Owó Méjì Tí Ìníyelórí Rẹ̀ Kéré
Fífi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tá a gbà ń ti ire Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn. Àmọ́ tí a ò bá fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́ ńkọ́?
Ìgbà kan wà tí Jésù rí òtòṣì opó kan tó sọ ẹyọ owó kéékèèké méjì tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí sínú àpótí ìṣúra tó wà nínú tẹ́ńpìlì. Ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà ló mú kí ó fi “gbogbo ohun tí ó ní sínú rẹ̀, gbogbo ohun ìní ìgbésí ayé rẹ̀” bó tilẹ̀ jẹ́ aláìní. (Máàkù 12:41-44) Ti pé Jésù kíyè sí i jẹ́ ká mọ̀ pé ohun ribiribi ni ọrẹ tí obìnrin náà ṣe jẹ́ lójú Ọlọ́run. Lọ́nà kan náà, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kò ka fifi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù bí ẹni pé àwọn Kristẹni tó rí jájẹ nìkan ló lè ṣe é. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí àpẹẹrẹ àwọn ará ní Makedóníà pé, láìka ti “ipò òṣì paraku wọn [sí] . . . [wọ́n] ń bẹ̀ wá ṣáá pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpàrọwà fún àǹfààní ìfúnni onínúrere.”—2 Kọ́r. 8:1-4.
Torí náà, tó bá jẹ́ pé ohun tí agbára wa gbé kò ju ohun tá a lè fi wé ‘owó ẹyọ méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré,’ ẹ jẹ́ ká máa rántí pé ení tere èjì tere ni nǹkan fi ń di púpọ̀. Tá a bá ń fúnni látọkàn wá, inú Jèhófà Baba wa ọ̀rún tó jẹ́ ọ̀làwọ́ á máa dùn sí wa, nítorí pé “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”—2 Kọ́r. 9:7.