Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 30
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 30
Orin 125 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 20 ìpínrọ̀ 1 sí 7, àti àpótí tó wà ní ojú ìwé 156 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jeremáyà 32-34 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. Fi ìṣẹ́jú kan tàbí méjì tọ́ka sí àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn ti oṣù May tó lè fa àwọn èèyàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, ìyẹn Ilé Ìṣọ́ ti oṣù May àti Jí! ti April–June. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí àwọn ìwé ìròyìn yìí, kó o sì ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn, kí wọ́n sì sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n á fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
15 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Ìṣe 4:1-13, 18-20. Jíròrò bí ìtàn yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
10 min: “Ẹyọ Owó Méjì Tí Ìníyelórí Rẹ̀ Kéré.” Àsọyé.
Orin 126 àti Àdúrà