Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní October 28, 2013.
1. Kí ló túmọ̀ sí láti ní “èrò inú ti Kristi”? (1 Kọ́r. 2:16) [Sept. 2, w08 7/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 7]
2. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà “sá fún àgbèrè”? (1 Kọ́r. 6:18) [Sept. 2, w08 7/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 9; w04 2/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 9]
3. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé kí àwọn obìnrin “máa dákẹ́ nínú àwọn ìjọ”? (1 Kọ́r. 14:34) [Sept. 9, w12 9/1 ojú ìwé 9, àpótí]
4. Kí ni àwọn alàgbà lónìí lè rí kọ́ látinú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú 2 Kọ́ríńtì 1:24? [Sept. 16, w13 1/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 2 sí 3]
5. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ṣe ohun tó wà nínú 2 Kọ́ríńtì 9:7? [Sept. 23, w09 2/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 17]
6. Báwo la ṣe lè jàǹfààní tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Gálátíà 6:4? [Sept. 30, w12 12/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 18]
7. Kí ló túmọ̀ sí “láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́”? (Éfé. 4:3) [Oct. 7, w12 7/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 7]
8. Ojú wo ni Pọ́ọ̀lù fi wo àwọn ohun tó ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn? (Fílí. 3:8) [Oct. 14, w12 3/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 12]
9. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sùn gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù ti ń ṣe”? (1 Tẹs. 5:6) [Oct. 21, w12 3/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 4]
10. Báwo ni ikú ìrúbọ tí Jésù kú ṣe jẹ́ “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí”? (1 Tím. 2:6) [Oct. 28, w11 6/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 11]