Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 28
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 28
Orin 31 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jl ojú ìwé 3 àti Ẹ̀kọ́ 1 sí 2 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Tímótì 1-6–2 Tímótì 1-4 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: “Báwo Lo Ṣe Máa Lo Àkókò Ọlidé Tó Ń Bọ̀?” Àsọyé.
10 min: Jẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Mọ Bí Ìhìn Rere Ṣe Wúlò Tó. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Jàǹfààní, ojú ìwé 159. Ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni lọni. Lo kókó kan tó jẹ àwọn èèyàn lógún ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín.
15 min: Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Dé Lásìkò. Ìjíròrò. (1) Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa lórí ṣíṣe nǹkan lásìkò? (Háb. 2:3) (2) Tá a bá ń dé lásìkò fún ìpàdé àti òde ẹ̀rí, báwo lèyí ṣe fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Jèhófà àti pé a gba tàwọn ẹlòmíì rò? (3) Tá a bá pẹ́ dé fún ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá, ìpalára wo lèyí máa ń ṣe fún àwùjọ àti ẹni tó ń darí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá? (4) Tá a bá dá àkókò fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù wa tàbí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé a máa pa dà wá, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká pa dà lọ ní àkókò tá a dá gan-an? (Mát. 5:37) (5) Kí làwọn nǹkan tá a lè ṣe tó máa jẹ́ ká máa dé sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lásìkò, tí a kò sì ní máa pẹ́ dé ìpàdé?
Orin 69 àti Àdúrà