ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp20 No. 3 ojú ìwé 13
  • Ẹni Tó Ń Ran Aláìní Lọ́wọ́ Máa Rí Ọ̀pọ̀ Ìbùkún

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹni Tó Ń Ran Aláìní Lọ́wọ́ Máa Rí Ọ̀pọ̀ Ìbùkún
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÍ ÌWÉ MÍMỌ́ SỌ
  • BÍ A ṢE LÈ RAN ALÁÌNÍ LỌ́WỌ́
  • Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ “Aláàánú Ará Samáríà”?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ǹjẹ́ o Mọrírì Ìrànlọ́wọ́ Jèhófà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Báwo Ni Ìwà Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà Ṣe Máa Kásẹ̀ Nílẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ǹjẹ́ o ‘Ní Ọrọ̀ Lọ́dọ̀ Ọlọ́run’?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
wp20 No. 3 ojú ìwé 13
Ọkùnrin kan ń fi àwòrán júwe ọ̀nà fún ẹnì kan.

Ṣé o lè ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn láìka ọjọ́ orí, orílẹ̀-èdè wọn tàbí ẹ̀sìn wọn sí?

Ẹni Tó Ń Ran Aláìní Lọ́wọ́ Máa Rí Ọ̀pọ̀ Ìbùkún

Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé nílò oúnjẹ àti ibùgbé. Àwọn kan ń fẹ́ ohun tó máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Tá a bá sapá láti ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká rí ojú rere àti ìbùkún Ọlọ́run?

OHUN TÍ ÌWÉ MÍMỌ́ SỌ

“Ẹni tó ń ṣojúure sí aláìní, Jèhófà ló ń yá ní nǹkan, á sì san án pa dà fún un nítorí ohun tó ṣe.”​—ÒWE 19:17.

BÍ A ṢE LÈ RAN ALÁÌNÍ LỌ́WỌ́

Jésù sọ àkàwé ọkùnrin kan táwọn olè dá lọ́nà, tí wọ́n ṣe léṣe, tí wọ́n sì fi sílẹ̀ kó kú. (Lúùkù 10:​29-37) Àjèjì kan rí ọkùnrin tí wọ́n ti ṣe léṣe yìí, ó dúró láti ràn án lọ́wọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ọmọ ìlú kan náà.

Ọkùnrin aláàánú yìí kọ́kọ́ tọ́jú ẹni tí wọ́n ṣe léṣe náà, ó pèsè ohun tó nílò, ó sì tù ú nínú kí ara rẹ̀ lè wálẹ̀.

Kí lá rí kọ́ nínú àkàwé yìí? Jésù kọ́ wa pé ká máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà tá a bá lè gbé e gbà. (Òwe 14:31) Ìwé Mímọ́ kọ́ wa pé Ọlọ́run máa tó fòpin sí ìyà àti ìṣẹ́ tó ń bá aráyé fínra. Àmọ́, a lè wá béèrè pé, báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ṣe é, ìgbà wo ló sì máa ṣe é? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e máa sọ ọ̀pọ̀ ìbùkún tí Ẹlẹ́dàá wa tó nífẹ̀ẹ́ wa ti pinnu pe òun máa fún wa.

“ỌLỌ́RUN KÒ FI MÍ SÍLẸ̀”!

Ohun tí àjèjì kan láti Gambia sọ

“Nígbà tí mo dé ilẹ̀ Yúróòpù, mi ò ní nǹkan kan, mi ò níṣẹ́, mi ò lówó, mi ò sì nílé. Àwọn ohun tí mo kọ́ látinú Ìwé Mímọ́ jẹ́ kí ń máa fọgbọ́n bójú tó ọ̀rọ̀ ara mi, kí n máa ṣiṣẹ́ kára, kí n sì máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ dípò kí n máa sọ pé kí wọ́n ràn mí lọ́wọ́. Ọlọ́run kò fi mí sílẹ̀, ó sì ti bù kún mi lọ́pọ̀lọpọ̀!”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́