Ṣó Dájú Pé Ọjọ́ Ọ̀la Ẹnì Kan Á Dáa Tó Bá Kàwé Dáadáa Tó Sì Lówó Rẹpẹtẹ?
Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ọkàn àwọn á balẹ̀, ọjọ́ ọ̀la àwọn á sì dáa táwọn bá kàwé dáadáa, táwọn sì rí towó ṣe. Wọ́n gbà pé tẹ́nì kan bá lọ sí yunifásítì, ìyẹn á jẹ́ kó wúlò níbi iṣẹ́, á jẹ́ kó lè ṣe ojúṣe ẹ̀ nínú ìdílé, á sì wúlò láwùjọ. Wọ́n tún gbà pé téèyàn bá kàwé dáadáa, á ríṣẹ́ tó ń mówó ńlá wọlé, téèyàn bá sì lówó rẹpẹtẹ, kò sí bí ò ṣe ní láyọ̀.
OHUN TỌ́PỌ̀ ÈÈYÀN RÒ
Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Zhang Chen lórílẹ̀-èdè Ṣáínà sọ pé: “Mo gbà pé tí mi ò bá fẹ́ tòṣì, àfi kí n lọ sí yunifásítì, torí ìyẹn ló máa jẹ́ kí n ríṣẹ́ gidi táá máa mówó ńlá wọlé, táá jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀, táá sì jẹ́ kí n láyọ̀.”
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá bí wọ́n ṣe máa lọ kàwé ní yunifásítì tó lórúkọ, tíyẹn bá tiẹ̀ gba pé kí wọ́n lọ sórílẹ̀-èdè míì, torí wọ́n gbà pé ìyẹn á jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀, kí ọjọ́ ọ̀la wọn sì dáa. Ohun tọ́pọ̀ èèyàn máa ń ṣe nìyẹn kó tó di pé àjàkálẹ̀ àrùn Corona kò jẹ́ káwọn èèyàn lọ sórílẹ̀-èdè míì. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìròyìn tí àjọ kan gbé jáde lọ́dún 2012, wọ́n sọ pé: “Ohun tó ju ìlàjì lára àwọn tó ń lọ kàwé lórílẹ̀-èdè míì ló wá láti ilẹ̀ Éṣíà.”
Ọ̀pọ̀ òbí ló máa ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè rán àwọn ọmọ wọn lọ sí yunifásítì lórílẹ̀-èdè míì. Qixiang tó wá láti orílẹ̀-èdè Taiwan sọ pé: “Àwọn òbí mi ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, àmọ́ wọ́n rí i pé àwọn rán àwa ọmọ wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin lọ sí yunifásítì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.” Bíi tọ̀pọ̀ ìdílé, àwọn òbí ẹ̀ jẹ gbèsè tó pọ̀ gan-an kí wọ́n tó lè rí owó iléèwé àwọn ọmọ wọn san.
OHUN TÓ SÁBÀ MÁA Ń GBẸ̀YÌN ÌPINNU TÍ WỌ́N ṢE
Nǹkan máa ń tojú sú ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lé bí wọ́n ṣe máa kàwé rẹpẹtẹ tàbí di olówó
Àwọn tó bá lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga máa ń láwọn àǹfààní kan lóòótọ́, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ibi tí wọ́n fojú sí, ọ̀nà kì í gbabẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ni ò ríṣẹ́ tó tẹ́ wọn lọ́rùn lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ ọdún kàwé, tí wọ́n sì ti jẹ gbèsè tó pọ̀ gan-an. Nínú ìwé ìròyìn Business Times tí wọ́n ń gbé jáde lórílẹ̀-èdè Singapore, Rachel Mui sọ pé: “Ńṣe làwọn tó ń jáde ní yunifásítì ń pọ̀ sí i ṣáá, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ni kò ríṣẹ́.” Jianjie tó kàwé débi téèyàn ń kàwé dé lórílẹ̀-èdè Taiwan sọ pé: “Kò síṣẹ́ níta, torí náà ọ̀pọ̀ ló ń ṣe iṣẹ́ tí ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ohun tí wọ́n kọ́ nílé ìwé.”
Kódà, tẹ́nì kan bá tiẹ̀ ríṣẹ́ tó bá ohun tó kọ́ nílé ìwé mu, nǹkan ṣì lè má rí bẹ́ni náà ṣe fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, yunifásítì kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni ọmọ ilẹ̀ Thailand kan tó ń jẹ́ Niran ti kàwé, ó sì ríṣẹ́ tó bá ohun tó kọ́ nílé ìwé mu. Ó sọ pé: “Ọwọ́ mi tẹ ohun tí mò ń wá lóòótọ́. Mo ríṣẹ́ tó ń mówó ńlá wọlé fún mi torí pé mo kàwé ní yunifásítì. Àmọ́, bówó tí mò ń gbà ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ niṣẹ́ náà ń gba ọ̀pọ̀ àkókò, tó sì ń tán mi lókun. Nígbà tó yá, ilé iṣẹ́ náà dá èyí tó pọ̀ jù lára àwọn òṣìṣẹ́ wọn dúró, wọ́n sì dá èmi náà dúró. Ìyẹn wá jẹ́ kí n rí i pé kò síṣẹ́ tó láyọ̀lé.”
Kódà, àwọn tó rí towó ṣe, tàwọn èèyàn sì gbà pé wọ́n ń gbé ìgbé ayé ìdẹ̀rùn ṣì máa ń níṣòro nínú ìdílé wọn, wọ́n máa ń ṣàìsàn, nǹkan sì lè yí pa dà fún wọn. Katsutoshi tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Japan sọ pé: “Mo rí towó ṣe lóòótọ́, àmọ́ inú àwọn èèyàn ò dùn sí mi, ṣe ni wọ́n ń jowú mi ṣáá, tí wọ́n sì ń ta kò mí.” Obìnrin kan tó ń jẹ́ Lam, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Vietnam sọ pé: “Mo máa ń rí i tọ́pọ̀ èèyàn ń wá bí wọ́n ṣe máa ríṣẹ́ táá máa mówó ńlá wọlé fún wọn, àmọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín, nǹkan ò kì í rí bí wọ́n ṣe rò torí ọkàn wọn kì í balẹ̀, wọn kì í láyọ̀, wọ́n sì máa ń sorí kọ́. Nígbà míì sì rèé, gbogbo wàhálà tí wọ́n ń ṣe lè kó bá ìlera wọn.”
Bíi ti Franklin, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wá rí i pé àwọn nǹkan pàtàkì míì wà téèyàn lè fayé ẹ̀ ṣe dípò kó máa lé báá ṣe kàwé rẹpẹtẹ tàbí báá ṣe di olówó. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti rí i pé á dáa káwọn máa hùwà tó dáa, káwọn sì máa ran àwọn míì lọ́wọ́, kí ọjọ́ ọ̀la àwọn lè dùn kó sì lóyin. Wọ́n gbà pé ìyẹn á sàn ju kí wọ́n máa fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn lé bí wọ́n ṣe máa kó ohun ìní jọ. Àmọ́, tẹ́nì kan bá ṣáà ti ń hùwà rere, tó sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ṣéyẹn mú kó dájú pé ọjọ́ ọ̀la ẹni náà á dáa? A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.