ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w24 July ojú ìwé 14-19
  • Máa Kíyè Sára Kó O Má Bàa Kó Sínú Ìdẹwò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Kíyè Sára Kó O Má Bàa Kó Sínú Ìdẹwò
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀWỌN APÁ IBO LÓ TI YẸ KÁ MÁA KÍYÈ SÁRA?
  • BÁ A ṢE LÈ MÁA KÍYÈ SÁRA
  • MÁA KÍYÈ SÁRA NÍGBÀ GBOGBO
  • ÀǸFÀÀNÍ TÁ A MÁA RÍ TÁ A BÁ Ń KÍYÈ SÁRA NÍGBÀ GBOGBO
  • Bó O Ṣe Lè Borí Èrò Tí Kò Tọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Bíborí Àìpé Ẹ̀dá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Bí O Ṣe Lè Borí Ìdẹwò
    Jí!—2014
  • “Máa Tẹ̀ Lé” Jésù, Lẹ́yìn Tó O Bá Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
w24 July ojú ìwé 14-19

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 29

ORIN 121 A Nílò Ìkóra-Ẹni-Níjàánu

Máa Kíyè Sára Kó O Má Bàa Kó Sínú Ìdẹwò

“Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa kó sínú ìdẹwò.”—MÁT. 26:41.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká sá fún ẹ̀ṣẹ̀, ká sì yẹra fún àwọn nǹkan tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀.

1-2. (a) Kí ni Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀? (b) Kí nìdí táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi sá fi í sílẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

JÉSÙ sọ pé: “Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń fẹ́, àmọ́ ẹran ara jẹ́ aláìlera.”a (Mát. 26:41b) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká rí i pé ó mọ̀ pé aláìpé ni wá àti pé a lè ṣàṣìṣe. Àmọ́ Jésù tún kìlọ̀ fún wa pé ká ṣọ́ra, ká má dá ara wa lójú jù. Kó tó di pé Jésù sọ̀rọ̀ yìí lálẹ́ ọjọ́ yẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ti fọ́nnu pé àwọn ò ní fi Jésù Ọ̀gá àwọn sílẹ̀ láé. (Mát. 26:35) Ohun tó dáa ni wọ́n ní lọ́kàn. Síbẹ̀, wọn ò mọ̀ pé tí àdánwò bá dé, ohun tí wọ́n sọ pé kò lè ṣelẹ̀ ló máa wá ṣẹlẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi kìlọ̀ fún wọn pé: “Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa kó sínú ìdẹwò.”—Mát. 26:41a.

2 Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò ṣọ́nà bí Jésù ṣe sọ. Nígbà tí wọ́n mú Jésù, ṣé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ dúró tì í àbí wọ́n sá fi í sílẹ̀? Torí pé wọn ò ṣọ́nà bí Jésù ṣe sọ, wọ́n ṣe ohun tí wọ́n sọ pé àwọn ò ní ṣe láé, wọ́n sá fi Jésù sílẹ̀.—Mát. 26:56.

Fọ́tò: Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀ wà nínú ọgbà Gẹ́tísémánì lálẹ́. 1. Jésù ń bá àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ sọ̀rọ̀. 2. Àwọn àpọ́sítélì ń sùn. 3. Àwọn àpọ́sítélì sá lọ nígbà tí wọ́n mú Jésù.

Jésù gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nímọ̀ràn pé kí wọ́n máa ṣọ́nà, kí wọ́n sì máa kíyè sára kí wọ́n má bàa kó sínú ìdẹwò, àmọ́ wọ́n sá fi í sílẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 1-2)


3. (a) Tá a bá fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, kí nìdí tí ò fi yẹ ká dá ara wa lójú jù? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Kò yẹ ká dá ara wa lójú jù, ká wá máa rò pé a ò lè ṣàṣìṣe. Lóòótọ́, a ti pinnu pé kò sóhun tó máa mú ká fi Jèhófà sílẹ̀. Síbẹ̀, ó yẹ ká máa rántí pé aláìpé ni wá, ìdẹwò sì lè mú ká ṣe ohun tí ò tọ́. (Róòmù 5:12; 7:21-23) Láìròtẹ́lẹ̀, nǹkan kan lè dẹ wá wò tó lè mú ká fẹ́ ṣe ohun tí ò tọ́. Torí náà, tá a bá fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti Ọmọ ẹ̀, ó yẹ ká fi ìkìlọ̀ Jésù sílò pé ká kíyè sára ká má bàa dẹ́ṣẹ̀. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ṣe é. Lákọ̀ọ́kọ́, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn apá ibi tó ti yẹ ká máa kíyè sára. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè yẹra fún ìdẹwò. Paríparí ẹ̀, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè máa kíyè sára nígbà gbogbo.

ÀWỌN APÁ IBO LÓ TI YẸ KÁ MÁA KÍYÈ SÁRA?

4-5. Kí nìdí tó fi yẹ ká kíyè sára ká má bàa dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ò tó nǹkan?

4 Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ò tó nǹkan lè ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n lè mú ká dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ míì tó burú jáì.

5 Gbogbo wa ni ìdẹwò lè dé bá láti ṣe ohun tí ò tọ́. Gbogbo wa la níbi tá a kù sí torí nǹkan ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló máa ń dẹ wá wò, ó lè jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, ìwà àìmọ́ tàbí ká máa hùwà báyé ṣe ń hùwà. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa wu ẹnì kan láti ṣèṣekúṣe. Ìṣòro ẹlòmíì ni pé ó máa ń wù ú láti lọ́wọ́ sí ìwà àìmọ́, bíi kó máa fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹ̀ tàbí kó máa wo àwòrán àti fíìmù ìṣekúṣe. Tẹnì kan ni pé ó máa ń bẹ̀rù èèyàn, tẹlòmíì ni pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni sọ ohun tóun máa ṣe fóun. Ó sì lè jẹ́ ìbínú fùfù tàbí nǹkan míì ló ń bá ẹnì kan fínra. Bí Jémíìsì ṣe sọ ọ́ ló rí, ó ní “àdánwò máa ń dé bá kálukú nígbà tí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ bá fà á mọ́ra, tó sì tàn án jẹ.”—Jém. 1:14.

6. Òótọ́ ọ̀rọ̀ wo ló yẹ kí kálukú bá ara ẹ̀ sọ?

6 Ṣé o mọ ìṣòro tìẹ, ìyẹn ohun tó máa ń dẹ ẹ́ wò? Ó léwu gan-an tá a bá ń rò pé a ò níṣòro kankan tàbí ká máa rò pé a ò lè dẹ́ṣẹ̀. (1 Jòh. 1:8) Ó ṣe tán, Pọ́ọ̀lù náà sọ pé àwọn tó “kúnjú ìwọ̀n nípa tẹ̀mí” náà lè dẹ́ṣẹ̀ tí wọn ò bá kíyè sára. (Gál. 6:1) Torí náà, ó yẹ kí kálukú bá ara ẹ̀ sọ òótọ́ ọ̀rọ̀, kó sì gbà pé òun níbi tóun kù sí.—2 Kọ́r. 13:5.

7. Kí ló yẹ ká máa kíyè sí lójú méjèèjì? Sọ àpèjúwe kan.

7 Tá a bá ti mọ àwọn nǹkan tó máa ń dẹ wá wò, kí ló yẹ ká ṣe? Ṣe gbogbo nǹkan tó o lè ṣe kó o má bàa kó sínú ìdẹwò náà. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ibi tó rọrùn jù fáwọn ọ̀tá láti gbà wọ ìlú olódi ni ẹnubodè rẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn ẹ̀ṣọ́ tó pọ̀ ló máa ń wà lẹ́nu ibodè. Lọ́nà kan náà, ó yẹ káwa náà máa kíyè sí ibi tá a kù sí lójú méjèèjì ká má bàa dẹ́ṣẹ̀.—1 Kọ́r. 9:27.

BÁ A ṢE LÈ MÁA KÍYÈ SÁRA

8-9. Kí ni ọ̀dọ́kùnrin tí ìwé Òwe orí 7 sọ̀rọ̀ ẹ̀ yẹ kó ṣe kó má bàa dẹ́ṣẹ̀ ńlá? (Òwe 7:8, 9, 13, 14, 21)

8 Báwo la ṣe lè máa kíyè sára? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè kọ́ lára ọ̀dọ́kùnrin tí ìwé Òwe orí 7 sọ̀rọ̀ ẹ̀. Ó bá obìnrin oníṣekúṣe kan sùn. Ẹsẹ 22 sọ pé ó tẹ̀ lé e “lójijì.” Àmọ́ bí àwọn ẹsẹ tó ṣáájú ẹsẹ yìí ṣe sọ, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ti ṣe kó tó dẹ́ṣẹ̀.

9 Kí ló mú kó dẹ́ṣẹ̀? Àkọ́kọ́, àṣálẹ́ ni “ó gba ojú ọ̀nà tó wà nítòsí ìyànà ilé [obìnrin oníṣekúṣe náà] kọjá.” Lẹ́yìn náà, ó rìn lọ sí ọ̀nà ilé ẹ̀. (Ka Òwe 7:8, 9.) Nígbà tó sì rí obìnrin náà, kò kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ó gbà kí obìnrin náà fẹnu ko òun lẹ́nu, ó sì fetí sí bó ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ tó rú, bóyá torí kí ọ̀dọ́kùnrin náà má bàa ronú pé ẹni burúkú ni. (Ka Òwe 7:13, 14, 21.) Ká sọ pé ọ̀dọ́kùnrin yẹn ti sá fáwọn ohun tó mú kó dẹ́ṣẹ̀, ì bá ti bọ́ lọ́wọ́ ìdẹwò, kò sì ní dẹ́ṣẹ̀.

10. Lákòókò tiwa yìí, báwo lẹnì kan ṣe lè ṣe irú àṣìṣe tí ọ̀dọ́kùnrin yẹn ṣe?

10 Ohun tí Sólómọ́nì sọ jẹ́ ká mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí ìránṣẹ́ Jèhófà kan. Ó lè dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kó sì rò pé ‘òjijì’ ló ṣẹlẹ̀. Ó sì lè sọ pé “Ó kàn ṣàdédé ṣẹlẹ̀ ni.” Síbẹ̀, tó bá ronú jinlẹ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, á rí i pé òun ti ṣe àwọn ìpinnu kan tí ò mọ́gbọ́n dání tó jẹ́ kóun dá ẹ̀ṣẹ̀ náà. Ó lè máa kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́, kó máa wo eré ìnàjú tí ò dáa tàbí kó máa ṣe é, ó sì lè máa lọ síbi tí ò yẹ kó lọ láàárín ìlú tàbí kó máa lọ síbi tí ò dáa lórí ìkànnì. Ó ṣeé ṣe kó má gbàdúrà mọ́, kó má ka Bíbélì mọ́, kó má lọ sípàdé mọ́, kó má sì wàásù mọ́. Bíi ti ọ̀dọ́kùnrin tí ìwé Òwe sọ, kì í ṣe ‘òjijì’ ló dẹ́ṣẹ̀.

11. Kí ló yẹ ká sá fún ká má bàa dẹ́ṣẹ̀?

11 Kí la rí kọ́? Ó yẹ ká sá fún ẹ̀ṣẹ̀ àti ohun tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀. Ohun tí Sólómọ́nì sọ nìyẹn nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀dọ́kùnrin àti obìnrin oníṣekúṣe yẹn. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ obìnrin náà, ó kìlọ̀ pé: “Má rìn gbéregbère wọ àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.” (Òwe 7:25) Ó tún sọ nípa obìnrin oníwàkiwà náà pé: “Jìnnà réré sí i; má sì sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀.” (Òwe 5:3, 8) Torí náà, tá ò bá fẹ́ dẹ́ṣẹ̀, ó yẹ ká jìnnà réré sí àwọn nǹkan tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀.b Lára àwọn nǹkan tó yẹ ká sá fún ni àwọn nǹkan tí ò burú tí Kristẹni lè ṣe, àmọ́ tó lè dẹ wá wò, tó sì lè mú ká ṣe ohun tí ò dáa.—Mát. 5:29, 30.

12. Kí ni Jóòbù pinnu pé òun ò ní ṣe, báwo nìyẹn ò ṣe jẹ́ kó dẹ́ṣẹ̀? (Jóòbù 31:1)

12 Tá ò bá fẹ́ ṣe ohun tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀, ó yẹ ká pinnu pé a ò ní ṣe ohun tí ò tọ́. Ohun tí Jóòbù ṣe nìyẹn. Ó “bá ojú [rẹ̀] dá májẹ̀mú” pé òun ò ní wo obìnrin láti bá a ṣèṣekúṣe. (Ka Jóòbù 31:1.) Tí Jóòbù ò bá yí ìpinnu ẹ̀ pa dà, kò ní ṣàgbèrè. Ó yẹ káwa náà pinnu pé a ò ní ṣe ohunkóhun tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀.

13. Kí nìdí tó fi yẹ ká kíyè sí ohun tá à ń rò? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

13 Ó tún yẹ ká kíyè sí ohun tá à ń rò. (Ẹ́kís. 20:17) Àwọn kan gbà pé táwọn bá ń ro ohun tí ò dáa àmọ́ táwọn ò tíì ṣe é, kò burú. Àmọ́, irú èrò yẹn ò dáa rárá torí pé bí ẹni náà bá ṣe ń ro ohun tí ò dáa, bẹ́ẹ̀ lá máa wù ú láti ṣe é. Tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń kó ara ẹ̀ sínú ìdẹwò nìyẹn, á sì ṣòro fún un láti kápá ẹ̀. Ká sòótọ́, kò sí bá a ṣe lè ṣe é tí èrò burúkú ò ní wá sí wa lọ́kàn. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ohun tó yẹ ká ṣe ni pé ká gbé èrò burúkú náà kúrò lọ́kàn lójú ẹsẹ̀, ká sì máa ro ohun tó dáa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, èrò burúkú tá ò ní lè kápá ẹ̀ ò ní gbilẹ̀ lọ́kàn wa, a ò sì ní dẹ́ṣẹ̀ ńlá.—Fílí. 4:8; Kól. 3:2; Jém. 1:13-15.

Fọ́tò: 1. Arákùnrin kan ń wo tẹlifíṣọ̀n lálẹ́. 2. Ó ń wo obìnrin tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. 3. Òun àti obìnrin náà jọ ń mutí nílé ọtí.

Ó yẹ ká sá fún ohunkóhun tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 13)


14. Nǹkan míì wo ni ò ní jẹ́ ká dẹ́ṣẹ̀?

14 Nǹkan míì wo la lè ṣe ká má bàa dẹ́ṣẹ̀? Nǹkan náà ni pé ó yẹ kó dá wa lójú pé tá a bá ń pa àwọn òfin Jèhófà mọ́, gbogbo ìgbà làá máa jàǹfààní ẹ̀. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè ṣòro fún wa láti máa ronú bí Jèhófà ṣe fẹ́, ó sì lè má wù wá láti ṣohun tó fẹ́, àmọ́ tá a bá ń sa gbogbo ipá wa láti máa ṣe ohun tó tọ́, ọkàn wa máa balẹ̀.

15. Tó bá ń wù wá láti ṣe ohun tó tọ́, báwo nìyẹn ò ṣe ní jẹ́ ká dẹ́ṣẹ̀?

15 Ó yẹ kó máa wù wá láti ṣe ohun tó tọ́. Tá a bá ń “kórìíra ohun búburú, [tá a] sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere,” á jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé ohun tó dáa làá máa ṣe, á sì jẹ́ ká máa sá fún ohun tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀. (Émọ́sì 5:15) Àǹfààní míì tí èrò tó dáa tún máa ṣe wá ni pé tí ìdẹwò bá dé bá wa lójijì, á jẹ́ ká lè borí ẹ̀.

16. Tá a bá gbájú mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká máa kíyè sára nígbà gbogbo? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

16 Kí la lè ṣe ká lè máa ṣe ohun tó tọ́? Ó yẹ ká túbọ̀ gbájú mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Tá a bá wà nípàdé ìjọ tàbí tá à ń wàásù, a kì í tètè kó sínú ìdẹwò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn nǹkan yìí máa ń jẹ́ ká ṣe ohun tínú Jèhófà dùn sí. (Mát. 28:19, 20; Héb. 10:24, 25) Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń ka Bíbélì déédéé, tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀, tá a sì ń ṣàṣàrò nípa ẹ̀, àá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ohun tó dáa, àá sì kórìíra ohun tó burú. (Jóṣ. 1:8; Sm. 1:2, 3; 119:97, 101) Rántí pé Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: ‘Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa kó sínú ìdẹwò.’ (Mát. 26:41) Tá a bá ń gbàdúrà sí Baba wa ọ̀run déédéé, á ràn wá lọ́wọ́, á sì fún wa lókun ká lè máa ṣe ohun tó fẹ́.—Jém. 4:8.

Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ ká sún mọ́ Jèhófà, kò ní jẹ́ ká kó sínú ìdẹwò (Wo ìpínrọ̀ 16)c


MÁA KÍYÈ SÁRA NÍGBÀ GBOGBO

17. Kùdìẹ̀-kudiẹ wo ni Pétérù ní tó mú kó ṣàṣìṣe ju ẹ̀ẹ̀kan lọ?

17 Ó ṣeé ṣe ká borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan pátápátá. Síbẹ̀, a lè láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ míì tó ń bá wa fínra nígbà gbogbo. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pétérù. Ìbẹ̀rù èèyàn ló mú kó sọ lẹ́ẹ̀mẹta pé òun ò mọ Jésù. (Mát. 26:69-75) Ó jọ pé Pétérù ti borí ìbẹ̀rù ẹ̀ nígbà tó fìgboyà sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run níwájú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn. (Ìṣe 5:27-29) Àmọ́ lẹ́yìn ọdún díẹ̀, kò bá àwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù jẹun mọ́ torí pé “ó ń bẹ̀rù àwọn tó dádọ̀dọ́.” (Gál. 2:11, 12) Torí náà, Pétérù tún bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù àwọn èèyàn torí pé ìbẹ̀rù yẹn ò tíì tán lára ẹ̀.

18. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá ò bá gbógun ti àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan tá a ní?

18 Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sáwa náà. Lọ́nà wo? Kùdìẹ̀-kudiẹ tá a rò pé a ti borí lè pa dà wá dẹ wá wò. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan sọ pé: “Odindi ọdún mẹ́wàá ni mi ò fi wo àwòrán àti fíìmù ìṣekúṣe, mo sì rò pé mo ti borí ẹ̀. Àmọ́ kò tíì lọ torí pé ó ti di bárakú fún mi, ó tún ń ṣe mí bíi pé kí n wò ó nígbà tó yá.” Inú wa dùn pé arákùnrin yẹn ò jẹ́ kó sú òun. Ó wá mọ̀ pé ó yẹ kóun máa sapá lójoojúmọ́ kóun má bàa wo ìwòkuwò, ó sì yẹ kóun máa ṣe bẹ́ẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé òun. Ìyàwó ẹ̀ àtàwọn alàgbà ìjọ ẹ̀ ló ràn án lọ́wọ́ kó lè gbógun ti àwòrán àti fíìmù ìṣekúṣe.

19. Kí ló yẹ ká ṣe sáwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ń dà wá láàmú léraléra?

19 Kí ló yẹ ká ṣe sáwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ń dà wá láàmú léraléra, ká má bàa pa dà sídìí ẹ̀? Ohun tó yẹ ká ṣe ni pé ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Jésù fún wa pé: “Ẹ máa ṣọ́nà.” Kódà láwọn ìgbà tá a bá rò pé a ò lè ṣe ohun tí ò dáa, ó ṣì yẹ ká máa kíyè sára, ká má bàa kó sínú ìdẹwò. (1 Kọ́r. 10:12) Torí náà, túbọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan tó ń jẹ́ kó o borí ẹ̀. Máa rántí ohun tí Òwe 28:14 sọ, ó ní: “Aláyọ̀ ni ẹni tó bá ń kíyè sára nígbà gbogbo.”—2 Pét. 3:14.

ÀǸFÀÀNÍ TÁ A MÁA RÍ TÁ A BÁ Ń KÍYÈ SÁRA NÍGBÀ GBOGBO

20-21. (a) Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń kíyè sára nígbà gbogbo ká má bàa kó sínú ìdẹwò? (b) Tá a bá ṣe ipa tiwa, kí ni Jèhófà máa ṣe fún wa? (2 Kọ́ríńtì 4:7)

20 Ẹ jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé gbogbo ohun tá a bá ń ṣe ká má bàa kó sínú ìdẹwò tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ tá a máa rí tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà ju “ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ tí kì í tọ́jọ́” lọ. (Héb. 11:25; Sm. 19:8) Ìdí sì ni pé Jèhófà dá wa ká lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà ẹ̀. (Jẹ́n. 1:27) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, a sì máa ní ìyè àìnípẹ̀kun.—1 Tím. 6:12; 2 Tím. 1:3; Júùdù 20, 21.

21 Òótọ́ ni pé “ẹran ara jẹ́ aláìlera.” Àmọ́ ìyẹn ò sọ pé a ò lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà. Jèhófà máa fún wa lágbára ká lè ṣe ohun tó tọ́. (Ka 2 Kọ́ríńtì 4:7.) Kíyè sí i pé agbára tó kọjá ti ẹ̀dá ni Jèhófà sọ pé òun máa fún wa. Àmọ́ agbára ti ẹ̀dá làwa ní, òun là ń lò lójoojúmọ́ ká má bàa kó sínú ìdẹwò, ipa tiwa sì nìyẹn. Torí náà tá a bá ṣe ipa tiwa, ó dájú pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà wa, ó sì máa fún wa lókun tá a nílò. (1 Kọ́r. 10:13) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa kíyè sára ká má bàa kó sínú ìdẹwò.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Àwọn apá ibo ló ti yẹ ká máa kíyè sára ká má bàa kó sínú ìdẹwò?

  • Kí làwọn nǹkan tá a lè ṣe ká má bàa kó sínú ìdẹwò?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká máa kíyè sára nígbà gbogbo?

ORIN 47 Máa Gbàdúrà sí Jèhófà Lójoojúmọ́

a ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: “Ẹ̀mí” tí Mátíù 26:41 sọ ni ohun tó ń mú ká ṣe nǹkan tàbí ohun tó ń jẹ́ ká mọ nǹkan lára. “Ẹran ara” ni àìpé tó máa ń jẹ́ ká dẹ́ṣẹ̀. Torí náà, ó lè wù wá láti ṣe ohun tó dáa, àmọ́ tá ò bá ṣọ́ra, a lè kó sínú ìdẹwò, ká sì ṣe ohun tí Bíbélì sọ pé kò dáa.

b Ẹni tó dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá máa rí ohun tó máa ràn án lọ́wọ́ nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 57 kókó 1-3 àti nínú àpilẹ̀kọ náà “Ọjọ́ Iwájú Ni Kó O Tẹjú Mọ́” nínú Ilé Ìṣọ́, November 2020, ojú ìwé 27-29, ìpínrọ̀ 12-17.

c ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ń ka ẹsẹ ojúmọ́ láàárọ̀, ó ń ka Bíbélì nígbà oúnjẹ ọ̀sán, ó sì lọ sípàdé àárín ọ̀sẹ̀ nírọ̀lẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́