ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 30
ORIN 36 À Ń Dáàbò Bo Ọkàn Wa
Àwọn Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Tá A Kọ́ Lára Àwọn Ọba Ísírẹ́lì
“Ẹ ó sì tún rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tó ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.”—MÁL. 3:18.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa mọ ohun tí Jèhófà sọ nípa àwọn ọba Ísírẹ́lì ká lè mọ ohun tó fẹ́ káwa ìránṣẹ́ ẹ̀ náà máa ṣe lónìí.
1-2. Kí ni Bíbélì sọ nípa àwọn ọba kan ní Ísírẹ́lì?
BÍBÉLÌ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọkùnrin tó lé ní ogójì (40) tí wọ́n jẹ́ ọba Ísírẹ́lì.a Kò sì fi nǹkan kan bò nípa ohun táwọn kan lára wọn ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn kan tó jẹ́ ọba dáadáa náà ṣe nǹkan tí ò dáa. Ọ̀kan lára àwọn ọba rere yìí ni Ọba Dáfídì. Jèhófà sọ pé: ‘Ìránṣẹ́ mi Dáfídì fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé mi, ó sì ṣe kìkì ohun tí ó tọ́ lójú mi.’ (1 Ọba 14:8) Síbẹ̀, ọkùnrin yìí bá obìnrin kan tó ti lọ́kọ ṣèṣekúṣe, ó sì tún ṣètò bí ọkọ ẹ̀ ṣe kú lójú ogun.—2 Sám. 11:4, 14, 15.
2 Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ àwọn ọba tó jẹ́ aláìṣòótọ́ tó ṣe nǹkan tó dáa. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Rèhóbóámù. Ó “ṣe ohun tó burú” lójú Jèhófà. (2 Kíró. 12:14) Síbẹ̀, nígbà tí Ọlọ́run sọ fún un pé kó jẹ́ kí ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì kúrò lábẹ́ àkóso rẹ̀, ó ṣègbọràn. Bákan náà, ó kọ́ àwọn ìlú olódi, ìyẹn sì ṣe àwọn èèyàn Ọlọ́run láǹfààní.—1 Ọba 12:21-24; 2 Kíró. 11:5-12.
3. Ìbéèrè pàtàkì wo ló yẹ ká dáhùn, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Àmọ́ ìbéèrè pàtàkì kan wà tó yẹ ká wá ìdáhùn ẹ̀. Tó bá jẹ́ pé ohun tó dáa àtohun tí ò dáa làwọn ọba Ísírẹ́lì ṣe, báwo ni Jèhófà ṣe mọ̀ bóyá wọ́n jẹ́ olóòótọ́ tàbí wọn kì í ṣe olóòótọ́? Tá a bá mọ ìdáhùn ìbéèrè yẹn, á jẹ́ ká mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ káwa náà ṣe lónìí. Torí náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́ta tí Jèhófà fi máa ń mọ̀ bóyá àwọn ọba Ísírẹ́lì jẹ́ olóòótọ́ àbí wọn kì í ṣe olóòótọ́. Àkọ́kọ́, ohun tó wà lọ́kàn wọn. Ìkejì, bóyá wọ́n ronú pìwà dà àbí wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ìkẹta, ọwọ́ tí wọ́n fi mú ìjọsìn tòótọ́.
WỌ́N FI GBOGBO ỌKÀN WỌN NÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ
4. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín àwọn ọba tó jẹ́ olóòótọ́ àtàwọn tó jẹ́ aláìṣòótọ́?
4 Àwọn ọba tó fi gbogbo ọkàn wọn jọ́sìn Jèhófà ló múnú ẹ̀ dùn.b Ọba rere kan tó ń jẹ́ Jèhóṣáfátì “fi gbogbo ọkàn rẹ̀ wá Jèhófà.” (2 Kíró. 22:9) Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa Jòsáyà, ó sọ pé: “Ṣáájú rẹ̀, kò sí ọba kankan tó dà bíi rẹ̀, tó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ . . . pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.” (2 Ọba 23:25) Ọba Sólómọ́nì tó ṣe nǹkan tí ò dáa nígbẹ̀yìn ayé ẹ̀ ńkọ́? Bíbélì sọ pé: “Kò . . . fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà.” (1 Ọba 11:4) Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa Ọba Ábíjámù tóun náà jẹ́ aláìṣòótọ́, ó sọ pé: “Kò . . . fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà.”—1 Ọba 15:3.
5. Kí ló ń mú kẹ́nì kan fi gbogbo ọkàn ẹ̀ sin Jèhófà?
5 Kí ló ń mú kẹ́nì kan fi gbogbo ọkàn ẹ̀ sin Jèhófà? Ẹni tó ń fi gbogbo ọkàn ẹ̀ sin Jèhófà ò ní máa sìn ín torí pé ó kàn gbà pé ohun tó yẹ kóun ṣe nìyẹn. Dípò bẹ́ẹ̀, ohun tó ń mú kó sin Jèhófà ni pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ látọkàn wá, ó sì bọ̀wọ̀ fún un. Á sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀.
6. Báwo la ṣe lè máa fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà nìṣó? (Òwe 4:23; Mátíù 5:29, 30)
6 Báwo la ṣe lè fara wé àwọn ọba tó jẹ́ olóòótọ́, ká sì máa fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà nìṣó? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń sá fún àwọn nǹkan tó lè mú ká ṣe ohun tí ò dáa. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń wo eré ìnàjú tí ò dáa, tá à ń kó ẹgbẹ́ búburú tàbí tá à ń ronú nípa bá a ṣe máa di ọlọ́rọ̀, ó lè ṣàkóbá fún wa. Torí náà, tá a bá rí i pé a ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà mọ́, ó yẹ ká tètè wá nǹkan ṣe sí i.—Ka Òwe 4:23; Mátíù 5:29, 30.
7. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká sá fáwọn nǹkan tó lè mú ká ṣe ohun tí ò dáa?
7 A ò gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó lè mú ká má fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà. Tá ò bá ṣọ́ra, a lè máa tan ara wa jẹ, ká máa rò pé tá a bá ṣáà ti ń lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà, kò sóhun tó máa ṣẹlẹ̀ tá a bá tiẹ̀ ń rìn ní bèbè ìwà burúkú. Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná. Ká sọ pé ò ń tún ilé ẹ ṣe lọ́jọ́ kan, àmọ́ o ṣí àwọn wíńdò àti ilẹ̀kùn ẹ sílẹ̀, afẹ́fẹ́ sì ń gbé eruku wọlé. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ibi tó o ti nù tẹ́lẹ̀? Ó dájú pé gbogbo ibi tó o ti nù yẹn máa pa dà dọ̀tí. Kí ni ẹ̀kọ́ ibẹ̀? Kì í ṣe pé ká kàn máa ka Bíbélì, ká sì máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà nìkan ni. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká má ṣe gba àwọn ìwà tínú Ọlọ́run ò dùn sí láyè, èyí tó dà bí eruku tí “afẹ́fẹ́” ayé yìí lè gbé wọnú ọkàn wa torí ó lè mú ká má fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà mọ́.—Éfé. 2:2.
WỌ́N RONÚ PÌWÀ DÀ Ẹ̀ṢẸ̀ WỌN
8-9. Kí ni Ọba Dáfídì àti Ọba Hẹsikáyà ṣe nígbà tí wọ́n bá wọn wí? (Wo àwòrán.)
8 Bá a ṣe sọ níṣàájú, Ọba Dáfídì dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an. Àmọ́ nígbà tí wòlíì Nátánì kò ó lójú láti sọ ohun tó ṣe fún un, Dáfídì rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀, ó sì ronú pìwà dà. (2 Sám. 12:13) Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ nínú Sáàmù 51 fi hàn lóòótọ́ pé ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Dáfídì ò díbọ́n pé òun ronú pìwà dà torí kó lè tan Nátánì jẹ tàbí torí kò fẹ́ jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀.—Sm. 51:3, 4, 17, àkọlé.
9 Ọba Hẹsikáyà náà dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà. Bíbélì sọ pé: “Ìgbéraga . . . wọ̀ ọ́ lẹ́wù, èyí sì fa ìbínú Ọlọ́run wá sórí rẹ̀ àti sórí Júdà àti Jerúsálẹ́mù.” (2 Kíró. 32:25) Kí ló sọ Hẹsikáyà di agbéraga? Ó lè jẹ́ torí ọrọ̀ tó ní, ó sì lè jẹ́ torí bó ṣe ṣẹ́gun àwọn ará Ásíríà tàbí torí bí Jèhófà ṣe wò ó sàn lọ́nà ìyanu. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbéraga náà ló mú kó fi ọrọ̀ tó ní han àwọn ará Bábílónì, ìyẹn ló sì mú kí wòlíì Àìsáyà bá a wí. (2 Ọba 20:12-18) Àmọ́ bíi ti Dáfídì, Hẹsikáyà ronú pìwà dà. (2 Kíró. 32:26) Torí náà, nígbà tí Jèhófà máa sọ̀rọ̀ nípa ọba yìí nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ó sọ pé olóòótọ́ ni, ó sì “ń ṣe ohun tí ó tọ́.”—2 Ọba 18:3.
Ọba Dáfídì àti Ọba Hẹsikáyà fi ìrẹ̀lẹ̀ ronú pìwà dà nígbà tí wọ́n bá wọn wí nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá (Wo ìpínrọ̀ 8-9)
10. Kí ni Ọba Amasááyà ṣe nígbà tí wòlíì Jèhófà bá a wí?
10 Amasááyà ọba Júdà ṣe ohun tó tọ́ ní tiẹ̀, “àmọ́ kì í ṣe pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀.” (2 Kíró. 25:2) Àṣìṣe wo ló ṣe? Lẹ́yìn tí Jèhófà ràn án lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọmọ Édómù, Amasááyà forí balẹ̀ fún òrìṣà wọn.c Nígbà tí wòlíì Jèhófà sì kò ó lójú, ó fàáké kọ́rí, kò sì gba ọ̀rọ̀ wòlíì náà.—2 Kíró. 25:14-16.
11. Bí 2 Kọ́ríńtì 7:9, 11 ṣe sọ, kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí Jèhófà tó lè dárí jì wá? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
11 Kí la kọ́ lára àwọn ọba yìí? Ohun tá a kọ́ ni pé ó yẹ ká ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wa, ká sì rí i pé a ò tún dẹ́ṣẹ̀ náà mọ́. Tó bá jẹ́ pé àwọn alàgbà ìjọ ló fún wa nímọ̀ràn ńkọ́, kódà kó jẹ́ nǹkan kékeré la ṣe? Kò yẹ ká máa rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa mọ́ tàbí pé àwọn alàgbà kórìíra wa. Kódà àwọn ọba rere tó jẹ ní Ísírẹ́lì kò kọjá ẹni tá à ń fún nímọ̀ràn àtẹni tá à ń bá wí. (Héb. 12:6) Tí wọ́n bá bá wa wí, ó yẹ ká (1) fìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí náà, (2) ká ṣàtúnṣe tó yẹ, (3) ká sì máa sin Jèhófà nìṣó tọkàntọkàn. Torí náà, tá a bá ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wa, Jèhófà máa dárí jì wá.—Ka 2 Kọ́ríńtì 7:9, 11.
Tí wọ́n bá bá wa wí, ó yẹ ká (1) fìrẹ̀lẹ̀ gbà á, (2) ká ṣàtúnṣe tó yẹ, ká sì (3) máa fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà nìṣó (Wo ìpínrọ̀ 11)f
WỌ́N FỌWỌ́ PÀTÀKÌ MÚ ÌJỌSÌN TÒÓTỌ́
12. Kí làwọn ọba tó jólóòótọ́ fi yàtọ̀ sáwọn ọba aláìṣòótọ́?
12 Àwọn ọba tí Jèhófà kà sí olóòótọ́ máa ń fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn tòótọ́. Wọ́n sì máa ń gba àwọn ará ìlú wọn níyànjú pé káwọn náà ṣe bẹ́ẹ̀. Bá a ṣe sọ ṣáájú, àwọn náà ní kùdìẹ̀-kudiẹ tiwọn. Àmọ́, wọ́n sin Jèhófà tọkàntọkàn, wọ́n sì ṣiṣẹ́ kára láti pa òrìṣà run ní orílẹ̀-èdè wọn.d
13. Kí nìdí tí Jèhófà fi ka Ọba Áhábù sí aláìṣòótọ́?
13 Kí làwọn ọba kan ṣe tí Jèhófà fi kà wọ́n sí aláìṣòótọ́? Ó dájú pé kì í ṣe gbogbo ohun táwọn ọba náà ṣe ló burú. Kódà Ọba Áhábù fìrẹ̀lẹ̀ hàn dé àyè kan, ó sì kábàámọ̀ pé òun lọ́wọ́ nínú ikú Nábótì. (1 Ọba 21:27-29) Yàtọ̀ síyẹn, ó kọ́ àwọn ìlú fún Ísírẹ́lì, ó sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn. (1 Ọba 20:21, 29; 22:39) Àmọ́ Áhábù ṣe ohun tó burú gan-an torí pé ìyàwó ẹ̀ mú kó gbé ìbọ̀rìṣà lárugẹ, kò sì ronú pìwà dà rárá.—1 Ọba 21:25, 26.
14. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé aláìṣòótọ́ ni Ọba Rèhóbóámù? (b) Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn ọba aláìṣòótọ́ bá ń ṣàkóso?
14 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ ọba míì tó jẹ́ aláìṣòótọ́, ìyẹn Ọba Rèhóbóámù. Bá a ṣe sọ ṣáájú, òun náà gbé nǹkan rere díẹ̀ ṣe nígbà àkóso ẹ̀. Àmọ́ nígbà tí ìjọba ẹ̀ fìdí múlẹ̀ tán, ó pa Òfin Jèhófà tì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀rìṣà. (2 Kíró. 12:1) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó ń ṣekuṣẹyẹ torí tó bá jọ́sìn Jèhófà díẹ̀, á tún bọ̀rìṣà díẹ̀. (1 Ọba 14:21-24) Kì í ṣe Rèhóbóámù àti Áhábù nìkan ni ọba tó pa ìjọsìn tòótọ́ tì. Ká sòótọ́, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọba aláìṣòótọ́ yẹn ló fara mọ́ ìbọ̀rìṣà. Ó hàn gbangba pé ọwọ́ tí ọba kan bá fi mú ìjọsìn tòótọ́ ni Jèhófà máa fi mọ̀ bóyá ọba rere ni tàbí ọba burúkú.
15. Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ ká fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn tòótọ́?
15 Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ ká fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn tòótọ́? Nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ọba ló máa ń tọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run sọ́nà, tí wọ́n sì máa ń kọ́ wọn láti jọ́sìn rẹ̀. Bákan náà, táwọn èèyàn bá ń jọ́sìn ọlọ́run èké, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, kí wọ́n sì máa hùwà ìkà sáwọn èèyàn. (Hós. 4:1, 2) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ti ya àwọn ọba Ísírẹ́lì àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí mímọ́ fún ara ẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé tí wọ́n bá lọ jọ́sìn àwọn ọlọ́run èké, àgbèrè ni wọ́n ṣe yẹn. (Jer. 3:8, 9) Tẹ́ni tó ṣègbéyàwó bá ṣàgbèrè, ìwà burúkú gbáà ló hù sẹ́nì kejì ẹ̀. Lọ́nà kan náà, tí ẹnì kan tó ti ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà bá ń lọ́wọ́ nínú ẹ̀sìn èké, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ló dá sí Jèhófà yẹn.e—Diu. 4:23, 24.
16. Báwo ni Jèhófà ṣe ń mọ ẹni tó jẹ́ olódodo àti ẹni burúkú?
16 Kí la kọ́? Ó yẹ ká pinnu pé a ò ní ṣe ẹ̀sìn èké. Àmọ́, a tún gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn tòótọ́, ká sì máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà. Wòlíì Málákì sọ bí Jèhófà ṣe máa ń mọ ẹni rere àti ẹni burúkú. Ó sọ pé: “Ẹ ó sì tún rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tó ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.” (Mál. 3:18) Torí náà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun, títí kan àìpé wa àtàwọn àṣìṣe tá a ṣe mú ká rẹ̀wẹ̀sì débi pé a ò ní sin Jèhófà mọ́. Ìdí sì ni pé ẹ̀ṣẹ̀ ńlá gbáà ni téèyàn ò bá sin Jèhófà mọ́.
17. Kí nìdí tó fi yẹ ká kíyè sára nípa ẹni tá a máa fẹ́?
17 Tó ò bá tíì ṣègbéyàwó àmọ́ tó o ṣì fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú, báwo ni ọ̀rọ̀ tí Málákì sọ nípa àwọn tó ń sin Ọlọ́run ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti yan ẹni tó tọ́? Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè láwọn ìwà tó dáa, àmọ́ tí onítọ̀hún ò bá tíì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́, ṣé a lè sọ pé olódodo ni lójú Jèhófà? (2 Kọ́r. 6:14) Tó bá jẹ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ lo fẹ́, ṣé ó máa jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run? Bí àpẹẹrẹ: Ó ṣeé ṣe káwọn obìnrin abọ̀rìṣà tí Ọba Sólómọ́nì fẹ́ láwọn ìwà kan tó dáa. Àmọ́ torí pé wọn ò jọ́sìn Jèhófà, díẹ̀díẹ̀ ni wọ́n mú kí Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀rìṣà.—1 Ọba 11:1, 4.
18. Kí ló yẹ kẹ́yin òbí máa kọ́ àwọn ọmọ yín?
18 Ẹ̀yin òbí, ẹ máa fi ìtàn àwọn ọba tó wà nínú Bíbélì kọ́ àwọn ọmọ yín kí wọ́n lè máa fìtara jọ́sìn Jèhófà. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn ọba tí Jèhófà sọ pé wọ́n jẹ́ olódodo làwọn ọba tó fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Jèhófà, tí wọ́n sì ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ fi ìwà àti ìṣe yín kọ́ àwọn ọmọ yín pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n máa ka Bíbélì déédéé, kí wọ́n máa lọ sípàdé, kí wọ́n sì máa wàásù déédéé àti pé àwọn nǹkan yìí ló gbọ́dọ̀ gbawájú nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe. (Mát. 6:33) Tẹ́ ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ yín á kàn máa sin Jèhófà torí pé ẹ̀yin òbí wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìyẹn lè mú kí wọ́n fi nǹkan míì sípò àkọ́kọ́ láyé wọn tàbí kí wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀ pátápátá.
19. Ṣé ìrètí kankan ṣì wà fáwọn tí ò sin Jèhófà mọ́? (Tún wo àpótí náà “O Ṣì Lè Pa Dà Sọ́dọ̀ Jèhófà!”)
19 Tẹ́nì kan ò bá sin Jèhófà mọ́, ṣé ó ṣì lè pa dà di ọ̀rẹ́ Jèhófà? Bẹ́ẹ̀ ni, torí ó lè ronú pìwà dà, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Jèhófà. Tó bá máa ṣe bẹ́ẹ̀, àfi kó nírẹ̀lẹ̀, kó sì gbà káwọn alàgbà ran òun lọ́wọ́. (Jém. 5:14) Ìsapá tẹ́ni náà máa ṣe tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, tó bá ṣáà ti máa mú kó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà!
20. Tá a bá fara wé àwọn ọba tó jẹ́ olóòótọ́, ojú wo ni Jèhófà máa fi wò wá?
20 Kí la ti kọ́ lára àwọn ọba tó jẹ ní Ísírẹ́lì? A máa dà bí àwọn ọba olóòótọ́ yẹn tá a bá ń sin Jèhófà tọkàntọkàn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn àṣìṣe tá a ṣe, ká ronú pìwà dà, ká sì ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. Ká sì máa rántí láti fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà. Tó o bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, á kà ẹ́ sí ẹni tó ń ṣe ohun tó tọ́ lójú ẹ̀.
ORIN 45 Àṣàrò Ọkàn Mi
a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, gbólóhùn náà “àwọn ọba Ísírẹ́lì” ń sọ nípa gbogbo àwọn ọba tó ṣàkóso àwọn èèyàn Ọlọ́run, bóyá èyí tó jẹ ní ẹ̀yà méjì ti Júdà, ẹ̀yà mẹ́wàá ti Ísírẹ́lì tàbí àwọn ọba tó jẹ ní gbogbo ẹ̀yà méjìlá (12) náà.
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Bíbélì sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” láti sọ irú ẹni tẹ́nì kan jẹ́ gangan, ohun tẹ́ni náà nífẹ̀ẹ́ sí, ohun tó ń rò, ìwà ẹ̀, ohun tó lè ṣe, ohun tó ń mú un ṣe nǹkan àtàwọn nǹkan tó ń lé.
c Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn ọba abọ̀rìṣà máa ń jọ́sìn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá ṣẹ́gun.
d Ọba Ásà dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an. (2 Kíró. 16:7, 10) Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé ó ṣe àwọn nǹkan tó dáa lójú Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà tí wòlíì Jèhófà kọ́kọ́ bá a wí, kò gbà, àmọ́ ó jọ pé nígbà tó yá, ó ronú pìwà dà. Àwọn nǹkan tó dáa tó ṣe lójú Jèhófà ju àwọn àṣìṣe ẹ̀ lọ. Ó hàn gbangba pé Jèhófà nìkan ni Ásà jọ́sìn, ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú ìbọ̀rìṣà kúrò nílẹ̀ náà.—1 Ọba 15:11-13; 2 Kíró. 14:2-5.
e A ti rí i kedere pé ìjọsìn wa ṣe pàtàkì lójú Jèhófà torí pé òfin méjì àkọ́kọ́ nínú Òfin Mósè sọ pé a ò gbọ́dọ̀ jọ́sìn ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun àfi Jèhófà.—Ẹ́kís. 20:1-6.
f ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Alàgbà kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ bá arákùnrin kan sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe ń mutí. Arákùnrin náà fìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí yẹn, ó ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ, ó sì ń fi gbogbo ọkàn ẹ̀ sin Jèhófà nìṣó.