ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwfq àpilẹ̀kọ 7
  • Ṣé Kristẹni Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Kristẹni Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
  • Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?
    Kí Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?
  • Ǹjẹ́ Ẹ Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Jésù?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ṣáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́ Pé Àwọn Nìkan Làwọn Máa Nígbàlà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìgbàlà Ohun Tí Ó Túmọ̀ Sí Gan-An
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
ijwfq àpilẹ̀kọ 7
Obìnrin kan ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Ṣé Kristẹni Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Bẹ́ẹ̀ ni. Kristẹni ni wá, àwọn ohun tá a fẹ́ sọ yìí ló fi hàn bẹ́ẹ̀:

  • A ń sapá láti tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ Jésù Kristi àti ìwà rẹ̀.—1 Pétérù 2:21.

  • A gbà gbọ́ pé ipasẹ̀ Jésù lèèyàn fi lè rí ìgbàlà, pé “kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run tí a ti fi fúnni láàárín àwọn ènìyàn nípasẹ̀ èyí tí a ó fi gbà wá là.”—Ìṣe 4:12.

  • Bí àwọn èèyàn bá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a máa ń ṣèrìbọmi fún wọn lórúkọ Jésù.—Mátíù 28:18, 19.

  • A máa ń gbàdúrà lórúkọ Jésù.—Jòhánù 15:16.

  • A gbà gbọ́ pé Jésù ni Orí, tàbí ẹni tí Ọlọ́run yàn láti jẹ́ aláṣẹ lórí gbogbo ọkùnrin.—1 Kọ́ríńtì 11:3.

Àmọ́ ṣá o, ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà, a yàtọ̀ sí àwọn ẹlẹ́sìn míì tí wọ́n ń pè ní Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, a gbà gbọ́ pé Bíbélì kọ́ni pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù, kì í ṣe ara Mẹ́talọ́kan. (Máàkù 12:29) A ò gbà pé ẹ̀mí èèyàn kì í kú, a ò gbà pé ibì kankan wà nínú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé Ọlọ́run máa ń dá àwọn èèyàn lóró títí láé nínú ọ̀run àpáàdì, tàbí pé àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọsìn gbọ́dọ̀ máa ní orúkọ òye tó gbé wọn ga ju àwọn yòókù lọ.—Oníwàásù 9:5; Ìsíkíẹ́lì 18:4; Mátíù 23:8-10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́