ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 26
  • Ǹjẹ́ Ọlọ́run Á Gbọ́ Mi Tí Mo Bá Gbàdúrà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ọlọ́run Á Gbọ́ Mi Tí Mo Bá Gbàdúrà?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Ṣé Jèhófà Máa Ń Tẹ́tí Gbọ́ Wa?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Ṣé Ọlọ́run Ń Gbọ́ Àdúrà Wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2021
  • Sísún Mọ́ Ọlọrun Nínú Àdúrà
    Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
  • Àǹfààní Pàtàkì Ni Àdúrà Jẹ́
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 26

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Á Gbọ́ Mi Tí Mo Bá Gbàdúrà?

Ohun tí Bíbélì sọ

Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run máa ń ran àwọn tó bá fi tinútinú tọrọ ohun tó bá bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Kódà tó ò bá tíì gbàdúrà rí, ó máa wú ẹ lórí tó o bá wo àpẹẹrẹ àwọn tí Bíbélì sọ pé wọ́n gbàdúrà pé “Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́.” Wò ó bí àpẹẹrẹ:

  • “Ran mi lọwọ, Oluwa Ọlọrun mi: gbà mi gẹgẹ bi ãnu rẹ.”—Orin Dafidi 109:26, Bibeli Mimọ.

  • “Aláìnì àti tálákà ni mí: Ọlọ́run jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́.”—Sáàmù 69:6, Douay Version.

Òótọ́ ni pé àwọn tó nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run làwọn tó kọ ọ̀rọ̀ yìí. Síbẹ̀, Ọlọ́run máa ń gbọ́ ti gbogbo ẹni tó bá tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú ẹ̀mí tó dára, irú bí àwọn “oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà” tàbí àwọn “tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀.”—Sáàmù 34:18.

Má ṣe rò pé Ọlọ́run jìnnà sí ọ kọjá kó fẹ́ mọ ohun tó ń dà ọ́ láàmú. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà ga, síbẹ̀síbẹ̀, ó ń rí onírẹ̀lẹ̀; Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbé ara rẹ̀ ga fíofío ni òun mọ̀ kìkì láti òkèèrè.” (Sáàmù 138:6) Kódà Jésù tiẹ̀ sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà.” (Mátíù 10:30) Ọlọ́run mọ̀ ọ́ kọjá ibi tó o mọ ara rẹ dé. Torí náà, ó máa tẹ́tí sí ọ tó bá gbàdúrà sí i pé kó bá ọ bójú tó àwọn ohun tó ò ń ṣàníyàn lé lórí!—1 Pétérù 5:7.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́