ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 17:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Tí ẹnikẹ́ni* bá jẹ òkú ẹran tàbí èyí tí ẹran inú igbó fà ya,+ ì báà jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ tàbí àjèjì ló jẹ ẹ́, kó fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì di aláìmọ́ títí di alẹ́;+ lẹ́yìn náà, á di mímọ́.

  • Léfítíkù 22:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Sọ fún wọn pé, ‘Jálẹ̀ àwọn ìran yín, èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ yín tó bá ṣì jẹ́ aláìmọ́, tó wá sún mọ́ àwọn ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yà sí mímọ́ fún Jèhófà, kí ẹ pa ẹni* náà kúrò níwájú mi.+ Èmi ni Jèhófà.

  • Léfítíkù 22:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Bákan náà, kò gbọ́dọ̀ jẹ òkú ẹran èyíkéyìí tàbí ohunkóhun tí ẹranko burúkú fà ya, kó sì di aláìmọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.+ Èmi ni Jèhófà.

  • Diutarónómì 14:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ òkú ẹran èyíkéyìí.+ Ẹ lè fún àjèjì tó wà nínú àwọn ìlú* yín, kó sì jẹ ẹ́ tàbí kí ẹ tà á fún àjèjì. Torí pé èèyàn mímọ́ lẹ jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run yín.

      “Ẹ ò gbọ́dọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.+

  • Ìsíkíẹ́lì 4:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Ní mo bá sọ pé: “Rárá o, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Láti kékeré títí di báyìí, mi* ò jẹ òkú ẹran rí tàbí ẹran tí wọ́n fà ya+ tó máa sọ mí di aláìmọ́, mi ò sì jẹ ẹran kankan tó jẹ́ aláìmọ́* rí.”+

  • Ìsíkíẹ́lì 44:31
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 Àwọn àlùfáà kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹyẹ tàbí ẹran kankan tó ti kú tàbí èyí tí ẹranko fà ya.’+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́