3 “‘Tí àlùfáà tí ẹ fòróró yàn+ bá dẹ́ṣẹ̀,+ tó sì mú kí àwọn èèyàn jẹ̀bi, kó mú akọ ọmọ màlúù kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá fún Jèhófà, kó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ tó dá.+ 4 Kó mú akọ màlúù náà wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé+ níwájú Jèhófà, kó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí akọ màlúù náà, kó sì pa á níwájú Jèhófà.+