9 Àmọ́ a rí Jésù, ẹni tí a mú kó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn áńgẹ́lì lọ,+ a ti fi ògo àti ọlá dé e ládé báyìí torí ó jìyà títí ó fi kú,+ kó lè tọ́ ikú wò fún gbogbo èèyàn nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.+
27 Kò nílò kó máa rúbọ lójoojúmọ́,+ bíi ti àwọn àlùfáà àgbà yẹn, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, lẹ́yìn náà fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn,+ torí ó ti ṣe èyí nígbà tó fi ara rẹ̀ rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé.+
7 àmọ́ àlùfáà àgbà nìkan ló máa ń wọ apá kejì lẹ́ẹ̀kan lọ́dún,+ kì í wọ ibẹ̀ láìsí ẹ̀jẹ̀,+ èyí tó fi máa ń rúbọ fún ara rẹ̀+ àti fún ẹ̀ṣẹ̀ táwọn èèyàn+ dá láìmọ̀ọ́mọ̀.
12 Kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti àwọn akọ ọmọ màlúù ló gbé wọnú ibi mímọ́, àmọ́ ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀ ni,+ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé, ó sì gba ìtúsílẹ̀* àìnípẹ̀kun fún wa.+