-
Nọ́ńbà 32:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Lẹ́yìn náà, wọ́n wá bá a, wọ́n sì sọ fún un pé: “Jẹ́ ká fi òkúta kọ́ ilé síbí fún àwọn ẹran ọ̀sìn wa, ká sì kọ́ ìlú fún àwọn ọmọ wa.
-
-
Nọ́ńbà 32:34-38Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Àwọn ọmọ Gádì kọ́* Díbónì,+ Átárótì,+ Áróérì,+ 35 Atiroti-ṣófánì, Jásérì,+ Jógíbéhà,+ 36 Bẹti-nímírà+ àti Bẹti-háránì,+ àwọn ìlú olódi, wọ́n sì fi òkúta kọ́ ilé fún àwọn agbo ẹran. 37 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì kọ́ Hẹ́ṣíbónì,+ Éléálè,+ Kíríátáímù,+ 38 Nébò+ àti Baali-méónì,+ wọ́n yí orúkọ àwọn ìlú náà pa dà, wọ́n kọ́ Síbúmà; wọ́n sì sọ àwọn ìlú tí wọ́n tún kọ́ ní orúkọ míì.
-