-
Ẹ́kísódù 40:36Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
36 Tí ìkùukùu bá ti kúrò lórí àgọ́ ìjọsìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa tú àgọ́ wọn ká bí wọ́n ṣe ń lọ láti ibì kan sí ibòmíì lẹ́nu gbogbo ìrìn àjò wọn.+
-
-
Nọ́ńbà 2:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 “Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun ibùdó Júdà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (186,400). Àwọn ni kó kọ́kọ́ máa tú àgọ́ wọn ká.+
-
-
Nọ́ńbà 2:16, 17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 “Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun ibùdó Rúbẹ́nì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kànléláàádọ́jọ ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti àádọ́ta (151,450), àwọn ni kó sì máa tú àgọ́ wọn ká ṣìkejì.+
17 “Nígbà tí ẹ bá ń gbé àgọ́ ìpàdé kúrò,+ àgọ́ àwọn ọmọ Léfì ni kó wà láàárín àwọn àgọ́ yòókù.
“Bí wọ́n bá ṣe pàgọ́ náà ni kí wọ́n ṣe tẹ̀ léra tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò,+ kí kálukú wà ní àyè rẹ̀, bí wọ́n ṣe pín ẹ̀yà wọn ní mẹ́ta-mẹ́ta.
-
-
Nọ́ńbà 2:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 “Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun ibùdó Éfúrémù jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìdínláàádọ́fà ó lé ọgọ́rùn-ún (108,100), àwọn ni kó sì máa tú àgọ́ wọn ká ṣìkẹta.+
-
-
Nọ́ńbà 2:31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 “Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ibùdó Dánì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́jọ ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (157,600). Àwọn ni kó máa tú àgọ́ wọn ká kẹ́yìn,+ bí wọ́n ṣe pín ẹ̀yà wọn ní mẹ́ta-mẹ́ta.”
-