-
Ẹ́kísódù 18:25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Mósè yan àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n nínú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì fi wọ́n ṣe olórí àwọn èèyàn náà, ó fi wọ́n ṣe olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta àti olórí àwọn mẹ́wàá-mẹ́wàá.
-
-
Jóṣúà 22:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá rán Fíníhásì+ ọmọ àlùfáà Élíásárì sí àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní ilẹ̀ Gílíádì, 14 ìjòyè mẹ́wàá sì bá a lọ, ìjòyè kan látinú agbo ilé kọ̀ọ̀kan ní gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ olórí agbo ilé bàbá rẹ̀ láàárín àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún* Ísírẹ́lì.+
-
-
1 Kíróníkà 27:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí, àwọn olórí nínú àwọn agbo ilé, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ àti àwọn aláṣẹ wọn tó ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba+ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ àwọn àwùjọ tó ń wọlé àti àwọn tó ń jáde ní oṣooṣù ní gbogbo oṣù tó wà nínú ọdún; ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ kọ̀ọ̀kan.
-