-
Nọ́ńbà 15:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 “‘Àmọ́ tó bá jẹ́ akọ lo mú wá látinú ọ̀wọ́ ẹran láti fi rú ẹbọ sísun+ tàbí ẹbọ láti fi san ẹ̀jẹ́ pàtàkì+ tàbí láti fi rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ fún Jèhófà,+ 9 kí o tún mú ọrẹ ọkà+ wá pẹ̀lú akọ ẹran tí o mú wá látinú ọ̀wọ́ ẹran. Kí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà, kó jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná tí o pò mọ́ òróró ìdajì òṣùwọ̀n hínì. 10 Kí o tún mú wáìnì wá láti fi ṣe ọrẹ ohun mímu,+ kó jẹ́ ìdajì òṣùwọ̀n hínì, kí o fi ṣe ọrẹ àfinásun tó ní òórùn dídùn* sí Jèhófà.
-