11 Ọmọkùnrin tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í tàbùkù sí Orúkọ náà, ó sì ń sọ̀rọ̀ òdì sí i.+ Torí náà, wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ Mósè.+ Ó ṣẹlẹ̀ pé, Ṣẹ́lómítì ni orúkọ ìyá rẹ̀, ọmọ Díbírì látinú ẹ̀yà Dánì. 12 Wọ́n fi ọmọkùnrin náà sínú àhámọ́ títí ìpinnu Jèhófà fi ṣe kedere sí wọn.+