12Míríámù àti Áárónì wá ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí Mósè torí ọmọ ilẹ̀ Kúṣì tó fi ṣe aya, torí pé ó fẹ́ ọmọbìnrin ará Kúṣì.+2 Wọ́n ń sọ pé: “Ṣé ẹnu Mósè nìkan ni Jèhófà gbà sọ̀rọ̀ ni? Ṣé kò gbẹnu tiwa náà sọ̀rọ̀ ni?”+ Jèhófà sì ń fetí sílẹ̀.+
2 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Mósè àti Áárónì,+ gbogbo àpéjọ náà sì ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí wọn pé: “Ó sàn ká ti kú sí ilẹ̀ Íjíbítì tàbí ká tiẹ̀ ti kú sínú aginjù yìí!