15 Wọ́n pa ọ̀nà tó tọ́ tì, a sì ti ṣì wọ́n lọ́nà. Wọ́n ṣe bíi ti Báláámù,+ ọmọ Béórì, ẹni tó nífẹ̀ẹ́ èrè ìwà àìtọ́,+ 16 àmọ́ a bá a wí torí ó ṣe ohun tí kò tọ́.+ Ẹran akẹ́rù tí kò lè sọ̀rọ̀ tó sọ̀rọ̀ bí èèyàn, kò jẹ́ kí wòlíì náà ṣe ohun tí kò bọ́gbọ́n mu.+