22 Mósè wá kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sílẹ̀ ní ọjọ́ yẹn, ó sì fi kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
23 Lẹ́yìn náà, Ó fa iṣẹ́ lé Jóṣúà+ ọmọ Núnì lọ́wọ́, ó sọ pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára,+ torí ìwọ lo máa mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ tí mo búra fún wọn nípa rẹ̀,+ mi ò sì ní fi ọ́ sílẹ̀.”