ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 17:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Ni Mósè bá sọ fún Jóṣúà+ pé: “Bá wa yan àwọn ọkùnrin, kí o sì lọ bá àwọn ọmọ Ámálékì jà. Ní ọ̀la, màá dúró sórí òkè, màá sì mú ọ̀pá Ọlọ́run tòótọ́ dání.”

  • Ẹ́kísódù 24:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Mósè gbéra pẹ̀lú Jóṣúà ìránṣẹ́ rẹ̀,+ Mósè sì lọ sórí òkè Ọlọ́run tòótọ́.+

  • Ẹ́kísódù 33:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ ní ojúkojú,+ bí ìgbà téèyàn méjì ń bá ara wọn sọ̀rọ̀. Nígbà tó pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn náà, Jóṣúà+ ọmọ Núnì, òjíṣẹ́ rẹ̀ àti ìránṣẹ́ rẹ̀+ ò kúrò níbi àgọ́ náà.

  • Nọ́ńbà 27:18-20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Mú Jóṣúà ọmọ Núnì, ọkùnrin tí ẹ̀mí wà nínú rẹ̀, kí o sì gbé ọwọ́ rẹ lé e.+ 19 Kí o wá mú un dúró níwájú àlùfáà Élíásárì àti gbogbo àpéjọ, kí o sì fa iṣẹ́ lé e lọ́wọ́ níṣojú+ wọn. 20 Kí o sì fún un+ lára àṣẹ* tí o ní, kí gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa gbọ́ tirẹ̀.+

  • Diutarónómì 31:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Jèhófà Ọlọ́run rẹ ló máa sọdá ṣáájú rẹ, òun fúnra rẹ̀ máa pa àwọn orílẹ̀-èdè yìí run kúrò níwájú rẹ, wàá sì lé wọn kúrò.+ Jóṣúà ló máa kó yín sọdá,+ bí Jèhófà ṣe sọ gẹ́lẹ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́