31 “Màá pààlà fún yín láti Òkun Pupa dé òkun àwọn Filísínì àti láti aginjù dé Odò;*+ torí màá mú kí ọwọ́ yín tẹ àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà, ẹ ó sì lé wọn kúrò níwájú yín.+
24 Gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ tẹ̀ ló máa di tiyín.+ Láti aginjù títí dé Lẹ́bánónì, láti Odò, ìyẹn odò Yúfírétì, dé òkun* tó wà ní ìwọ̀ oòrùn ló máa jẹ́ ààlà yín.+