ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 13:1-5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 “Tí ẹnì kan bá di wòlíì tàbí tó bẹ̀rẹ̀ sí í fi àlá sọ tẹ́lẹ̀ láàárín rẹ, tó sì fún ọ ní àmì tàbí tó sọ ohun kan tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ fún ọ, 2 tí àmì náà tàbí ohun tó sọ fún ọ sì ṣẹ, tó wá ń sọ pé, ‘Jẹ́ ká tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì,’ àwọn ọlọ́run tí o kò mọ̀, ‘sì jẹ́ ká máa sìn wọ́n,’ 3 o ò gbọ́dọ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ wòlíì yẹn tàbí ti alálàá yẹn,+ torí Jèhófà Ọlọ́run yín ń dán yín wò+ kó lè mọ̀ bóyá ẹ fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín.+ 4 Jèhófà Ọlọ́run yín ni kí ẹ máa tọ̀ lẹ́yìn, òun ni kí ẹ máa bẹ̀rù, àwọn àṣẹ rẹ̀ ni kí ẹ máa pa mọ́, ohùn rẹ̀ sì ni kí ẹ máa fetí sí; òun ni kí ẹ máa sìn, òun sì ni kí ẹ rọ̀ mọ́.+ 5 Àmọ́ kí ẹ pa wòlíì yẹn tàbí alálàá yẹn,+ torí ó fẹ́ mú kí ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run yín, kó lè mú yín kúrò ní ọ̀nà tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa láṣẹ pé kí ẹ máa rìn, ẹni tó mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, tó sì rà yín pa dà kúrò ní ilé ẹrú. Kí ẹ mú ohun tó burú kúrò láàárín yín.+

  • Jeremáyà 28:11-17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Hananáyà sì sọ lójú gbogbo àwọn èèyàn náà pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Bí màá ṣe ṣẹ́ àjàgà Nebukadinésárì ọba Bábílónì kúrò ní ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè nìyí kí ọdún méjì tó pé.’”+ Wòlíì Jeremáyà sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.

      12 Lẹ́yìn tí wòlíì Hananáyà ti ṣẹ́ ọ̀pá àjàgà tó mú kúrò lọ́rùn wòlíì Jeremáyà, Jèhófà wá sọ fún Jeremáyà pé: 13 “Lọ sọ fún Hananáyà pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “O ti ṣẹ́ ọ̀pá àjàgà igi,+ àmọ́ dípò rẹ̀, ọ̀pá àjàgà irin lo máa ṣe.” 14 Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Màá fi ọ̀pá àjàgà irin sí ọrùn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yìí, láti sin Nebukadinésárì ọba Bábílónì, wọ́n sì gbọ́dọ̀ sìn ín.+ Kódà màá fún un ní àwọn ẹran inú igbó.”’”+

      15 Wòlíì Jeremáyà wá sọ fún wòlíì Hananáyà+ pé: “Jọ̀wọ́, fetí sílẹ̀, ìwọ Hananáyà! Jèhófà kò rán ọ, àmọ́ o ti mú kí àwọn èèyàn yìí gbẹ́kẹ̀ lé irọ́.+ 16 Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Wò ó! Màá mú ọ kúrò lórí ilẹ̀. Ọdún yìí ni wàá kú, nítorí o ti mú kí àwọn èèyàn dìtẹ̀ sí Jèhófà.’”+

      17 Torí náà, wòlíì Hananáyà kú ní ọdún yẹn, ní oṣù keje.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́