ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Onídàájọ́ 3:9, 10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́,+ Jèhófà yan ẹnì kan tó máa gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀,+ ìyẹn Ótíníẹ́lì+ ọmọ Kénásì, àbúrò Kélẹ́bù. 10 Ẹ̀mí Jèhófà bà lé e,+ ó sì di onídàájọ́ Ísírẹ́lì. Nígbà tó lọ jagun, Jèhófà fi Kuṣani-ríṣátáímù ọba Mesopotámíà* lé e lọ́wọ́, ó sì ṣẹ́gun Kuṣani-ríṣátáímù.

  • Àwọn Onídàájọ́ 11:29
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 29 Ẹ̀mí Jèhófà wá bà lé Jẹ́fútà,+ ó sì gba Gílíádì àti Mánásè kọjá lọ sí Mísípè ti Gílíádì,+ láti Mísípè ti Gílíádì ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì.

  • Àwọn Onídàájọ́ 13:24, 25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Lẹ́yìn náà, obìnrin náà bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ ọ́ ní Sámúsìn;+ bí ọmọ náà ṣe ń dàgbà, Jèhófà ń bù kún un. 25 Nígbà tó yá, ẹ̀mí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í darí rẹ̀+ ní Mahane-dánì,+ láàárín Sórà àti Éṣítáólì.+

  • Àwọn Onídàájọ́ 14:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Àmọ́ ẹ̀mí Jèhófà fún un lágbára,+ ó sì fà á ya sí méjì, bí èèyàn ṣe ń fi ọwọ́ lásán fa ọmọ ewúrẹ́ ya sí méjì. Àmọ́ kò sọ ohun tó ṣe fún bàbá àti ìyá rẹ̀.

  • Àwọn Onídàájọ́ 15:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Nígbà tó dé Léhì, àwọn Filísínì kígbe ayọ̀ bí wọ́n ṣe rí i. Nígbà náà, ẹ̀mí Jèhófà fún un lágbára,+ àwọn okùn tí wọ́n fi de ọwọ́ rẹ̀ wá dà bíi fọ́nrán òwú ọ̀gbọ̀ tí iná jó gbẹ, àwọn ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ sì yọ́.+

  • Sekaráyà 4:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Ó wá sọ fún mi pé: “Ohun tí Jèhófà sọ fún Serubábélì nìyí: ‘“Kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn ọmọ ogun tàbí nípasẹ̀ agbára,+ bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́