-
Léfítíkù 11:23, 24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Gbogbo ẹ̀dá abìyẹ́ yòókù tó ń gbá yìn-ìn, tó ní ẹsẹ̀ mẹ́rin jẹ́ ohun ìríra fún yín. 24 Ẹ lè fi nǹkan wọ̀nyí sọ ara yín di aláìmọ́. Gbogbo ẹni tó bá fara kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí di alẹ́.+
-
-
Léfítíkù 15:4, 5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 “‘Ibùsùn èyíkéyìí tí ẹni tí ohun kan ń dà jáde lára rẹ̀ bá dùbúlẹ̀ sí yóò di aláìmọ́, ohunkóhun tó bá sì jókòó lé yóò di aláìmọ́. 5 Kí ẹni tó bá fara kan ibùsùn rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+
-
-
Nọ́ńbà 19:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Ẹnikẹ́ni tó bá wà ní pápá tó sì fara kan ẹni tí wọ́n fi idà pa tàbí òkú tàbí egungun èèyàn tàbí ibi ìsìnkú yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje.+
-