-
Jóṣúà 3:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 wọ́n sì pàṣẹ fún àwọn èèyàn náà pé: “Gbàrà tí ẹ bá rí i tí àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà+ gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ gbéra láti àyè yín, kí ẹ sì tẹ̀ lé e.
-
-
1 Kíróníkà 15:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ìgbà náà ni Dáfídì sọ pé: “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ àfi àwọn ọmọ Léfì, nítorí àwọn ni Jèhófà yàn láti máa gbé Àpótí Jèhófà àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún òun nígbà gbogbo.”+
-
-
1 Kíróníkà 15:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Nígbà náà, àwọn ọmọ Léfì fi àwọn ọ̀pá+ gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ lé èjìká wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Mósè pa látọ̀dọ̀ Jèhófà.
-