ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 13:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Àmọ́ ní báyìí, ìjọba rẹ kò ní pẹ́.+ Jèhófà máa wá ọkùnrin kan tí ọkàn rẹ̀ fẹ́,+ Jèhófà sì máa yàn án ṣe aṣáájú lórí àwọn èèyàn rẹ̀,+ nítorí pé o ò ṣègbọràn sí ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún ọ.”+

  • 1 Sámúẹ́lì 15:27, 28
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 Bí Sámúẹ́lì ṣe ń yíjú pa dà láti lọ, Sọ́ọ̀lù gbá etí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ tí kò lápá mú, aṣọ náà bá fà ya. 28 Sámúẹ́lì wá sọ fún un pé: “Jèhófà ti fa ìṣàkóso Ísírẹ́lì ya kúrò lọ́wọ́ rẹ lónìí, yóò sì fún ọmọnìkejì rẹ tó sàn jù ọ́ lọ.+

  • 1 Sámúẹ́lì 16:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Níkẹyìn, Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Ìgbà wo lo máa ṣọ̀fọ̀ Sọ́ọ̀lù dà,+ ní báyìí tí mo ti kọ Sọ́ọ̀lù pé kí ó má ṣe jẹ́ ọba lórí Ísírẹ́lì mọ́?+ Rọ òróró sínú ìwo,+ kí o sì lọ. Màá rán ọ lọ sọ́dọ̀ Jésè+ ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, nítorí mo ti yan ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ́ ọba fún mi.”+

  • 1 Sámúẹ́lì 16:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Torí náà, Sámúẹ́lì mú ìwo tí òróró wà nínú rẹ̀,+ ó sì fòróró yàn án lójú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ẹ̀mí Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í fún Dáfídì lágbára láti ọjọ́ náà lọ.+ Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì dìde, ó sì gba Rámà lọ.+

  • Sáàmù 89:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  3 “Mo ti bá àyànfẹ́ mi dá májẹ̀mú;+

      Mo ti búra fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé:+

  • Sáàmù 89:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Mo ti rí Dáfídì ìránṣẹ́ mi;+

      Mo ti fi òróró mímọ́ mi yàn án.+

  • Sáàmù 132:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Màá mú kí agbára Dáfídì pọ̀ sí i* níbẹ̀.

      Mo ti ṣètò fìtílà fún ẹni àmì òróró mi.+

  • Ìṣe 13:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Lẹ́yìn tó mú un kúrò, ó gbé Dáfídì dìde láti jẹ́ ọba wọn,+ ẹni tó jẹ́rìí nípa rẹ̀, tó sì sọ pé: ‘Mo ti rí Dáfídì ọmọ Jésè,+ ẹni tí ọkàn mi fẹ́;+ yóò ṣe gbogbo ohun tí mo fẹ́.’

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́