-
2 Kíróníkà 14:2-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ásà ṣe ohun tó dára tó sì tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. 3 Ó mú àwọn pẹpẹ àjèjì+ àti àwọn ibi gíga kúrò, ó fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà sí wẹ́wẹ́,+ ó sì gé àwọn òpó òrìṣà lulẹ̀.*+ 4 Yàtọ̀ síyẹn, ó sọ fún Júdà pé kí wọ́n wá Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, kí wọ́n sì máa pa Òfin àti àṣẹ rẹ̀ mọ́. 5 Torí náà, ó mú àwọn ibi gíga àti àwọn pẹpẹ tùràrí kúrò ní gbogbo àwọn ìlú Júdà,+ ìjọba náà sì wà láìsí ìyọlẹ́nu lábẹ́ àbójútó rẹ̀.
-
-
2 Kíróníkà 14:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ásà wá ké pe Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀,+ ó ní: “Jèhófà, kò jẹ́ nǹkan kan lójú rẹ bóyá àwọn tí o fẹ́ ràn lọ́wọ́ pọ̀ tàbí wọn ò lágbára. + Ràn wá lọ́wọ́, Jèhófà Ọlọ́run wa, nítorí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé,*+ a wá ní orúkọ rẹ láti dojú kọ ọ̀pọ̀ èèyàn yìí.+ Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run wa. Má ṣe jẹ́ kí ẹni kíkú borí rẹ.”+
-