7 Ìgbà náà ni Sólómọ́nì kọ́ ibi gíga+ kan fún Kémóṣì, ọlọ́run ìríra Móábù, lórí òkè tó wà níwájú Jerúsálẹ́mù, ó sì tún kọ́ òmíràn fún Mólékì,+ ọlọ́run ìríra àwọn ọmọ Ámónì.+
22 Júdà ń ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà,+ wọ́n fi ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá mú un bínú ju bí àwọn baba ńlá wọn ṣe mú un bínú lọ.+23 Àwọn náà ń kọ́ ibi gíga àti àwọn ọwọ̀n òrìṣà pẹ̀lú àwọn òpó òrìṣà*+ fún ara wọn sórí gbogbo òkè+ àti sábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.+