-
1 Àwọn Ọba 21:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Torí náà, Áhábù wá sínú ilé rẹ̀, ó dì kunkun, ó sì dorí kodò nítorí èsì tí Nábótì ará Jésírẹ́lì fún un, nígbà tó sọ pé: “Mi ò ní fún ọ ní ogún àwọn baba ńlá mi.” Ó wá dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ̀, ó gbé ojú sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó kọ̀, kò jẹun.
-
-
1 Àwọn Ọba 21:20-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Áhábù sọ fún Èlíjà pé: “O ti wá mi kàn, ìwọ ọ̀tá mi!”+ Ó dáhùn pé: “Mo ti wá ọ kàn. ‘Nítorí o ti pinnu* láti máa ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà,+ 21 màá mú àjálù bá ọ, màá gbá ọ dà nù bí ẹni gbálẹ̀, màá sì pa gbogbo ọkùnrin* ilé Áhábù run,+ títí kan àwọn aláìní àti àwọn aláìníláárí ní Ísírẹ́lì.+ 22 Màá sì ṣe ilé rẹ bí ilé Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì àti bí ilé Bááṣà+ ọmọ Áhíjà, nítorí o ti mú mi bínú, o sì ti mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.’
-