-
2 Kíróníkà 21:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Nígbà tí Jèhórámù gorí ìtẹ́ ìjọba bàbá rẹ̀, ó fi idà pa gbogbo àwọn àbúrò rẹ̀+ àti àwọn kan lára àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ipò rẹ̀ fìdí múlẹ̀.
-
-
2 Kíróníkà 22:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Nígbà tí Ataláyà,+ ìyá Ahasáyà rí i pé ọmọ òun ti kú, ó dìde, ó sì pa gbogbo ìdílé ọba* ilé Júdà run.+ 11 Àmọ́, Jèhóṣábéátì ọmọbìnrin ọba gbé Jèhóáṣì+ ọmọ Ahasáyà, ó jí i gbé láàárín àwọn ọmọ ọba tí wọ́n fẹ́ pa, ó sì fi òun àti obìnrin tó ń tọ́jú rẹ̀ sínú yàrá inú lọ́hùn-ún. Jèhóṣábéátì ọmọbìnrin Ọba Jèhórámù+ (òun ni ìyàwó àlùfáà Jèhóádà,+ òun náà sì ni arábìnrin Ahasáyà) rọ́nà fi í pa mọ́ nítorí Ataláyà, kó má bàa pa á.+ 12 Ọdún mẹ́fà ló fi wà lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n tọ́jú rẹ̀ pa mọ́ sí ilé Ọlọ́run tòótọ́, Ataláyà sì ń ṣàkóso ilẹ̀ náà.
-