-
1 Àwọn Ọba 16:30-33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Ìwà Áhábù ọmọ Ómírì tún wá burú lójú Jèhófà ju ti gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀.+ 31 Àfi bíi pé nǹkan kékeré ni lójú rẹ̀ bó ṣe ń rìn nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì, ó tún fẹ́ Jésíbẹ́lì+ ọmọ Etibáálì, ọba àwọn ọmọ Sídónì,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí í sin Báálì,+ ó sì ń forí balẹ̀ fún un. 32 Yàtọ̀ síyẹn, ó mọ pẹpẹ kan fún Báálì ní ilé* Báálì+ tí ó kọ́ sí Samáríà. 33 Áhábù tún ṣe òpó òrìṣà.*+ Áhábù sì ṣe ohun tó bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì nínú ju gbogbo àwọn ọba Ísírẹ́lì tó jẹ ṣáájú rẹ̀ lọ.
-