-
2 Kíróníkà 14:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ásà wá ké pe Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀,+ ó ní: “Jèhófà, kò jẹ́ nǹkan kan lójú rẹ bóyá àwọn tí o fẹ́ ràn lọ́wọ́ pọ̀ tàbí wọn ò lágbára. + Ràn wá lọ́wọ́, Jèhófà Ọlọ́run wa, nítorí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé,*+ a wá ní orúkọ rẹ láti dojú kọ ọ̀pọ̀ èèyàn yìí.+ Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run wa. Má ṣe jẹ́ kí ẹni kíkú borí rẹ.”+
-
-
2 Kíróníkà 18:31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 Gbàrà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rí Jèhóṣáfátì, wọ́n sọ lọ́kàn ara wọn pé: “Ọba Ísírẹ́lì nìyí.” Nítorí náà, wọ́n yíjú sí i láti bá a jà; Jèhóṣáfátì sì bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́,+ Jèhófà ràn án lọ́wọ́, Ọlọ́run sì darí wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
-