29 Ní ti ìyókù ìtàn Sólómọ́nì,+ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ wòlíì Nátánì,+ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Áhíjà+ ọmọ Ṣílò àti nínú àkọsílẹ̀ àwọn ìran Ídò+ aríran tó sọ nípa Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì?
15 Ní ti ìtàn Rèhóbóámù, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ wòlíì Ṣemáyà+ àti ti Ídò+ aríran tó wà nínú ìtàn ìdílé? Ìgbà gbogbo ni ogun ń wáyé láàárín Rèhóbóámù àti Jèróbóámù.+