-
2 Kíróníkà 28:22, 23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Nígbà tí Ọba Áhásì wà nínú ìdààmú, ńṣe ló túbọ̀ ń hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà. 23 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í rúbọ sí àwọn ọlọ́run àwọn ará Damásíkù + tí wọ́n ṣẹ́gun rẹ̀,+ ó ń sọ pé: “Nítorí pé àwọn ọlọ́run àwọn ọba Síríà ń ràn wọ́n lọ́wọ́, èmi náà á rúbọ sí wọn kí wọ́n lè ràn mí lọ́wọ́.”+ Àmọ́ ńṣe ni wọ́n ṣàkóbá fún òun àti gbogbo Ísírẹ́lì.
-
-
Jeremáyà 44:21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 “Ẹbọ tí ẹ rú, tí àwọn baba ńlá yín, àwọn ọba yín, àwọn ìjòyè yín àti àwọn èèyàn ilẹ̀ náà rú ní àwọn ìlú Júdà àti ní àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù,+ ni Jèhófà ti rántí, wọ́n sì wá sí i lọ́kàn!
-