-
Nọ́ńbà 18:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Jèhófà tún sọ fún Áárónì pé: “Èmi fúnra mi fi gbogbo ọrẹ tí wọ́n bá ṣe fún mi+ sí ìkáwọ́ rẹ. Mo ti fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lára gbogbo ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fi ṣe ọrẹ, kó jẹ́ ìpín+ yín títí lọ. 9 Èyí ló máa jẹ́ tìrẹ nínú ọrẹ mímọ́ jù lọ tí wọ́n fi iná sun: gbogbo ọrẹ tí wọ́n bá mú wá, títí kan àwọn ọrẹ ọkà+ wọn àtàwọn ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ wọn pẹ̀lú àwọn ẹbọ ẹ̀bi+ wọn tí wọ́n mú wá fún mi. Ohun mímọ́ jù lọ ló jẹ́ fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ.
-