19 Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá ti mú kí o sinmi lọ́wọ́ gbogbo ọ̀tá rẹ tó yí ọ ká, ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún,+ kí o pa orúkọ Ámálékì rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run.+ O ò gbọ́dọ̀ gbàgbé.
32 Sámúẹ́lì wá sọ pé: “Ẹ mú Ágágì ọba Ámálékì sún mọ́ mi.” Ni ara bá ń ti Ágágì láti* lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ nítorí Ágágì ń sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: ‘Ó dájú pé ikú* ti yẹ̀ lórí mi.’