12 màá ṣe ohun tí o béèrè.+ Màá fún ọ ní ọkàn ọgbọ́n àti òye,+ tó fi jẹ́ pé bí kò ṣe sí ẹni tó dà bí rẹ ṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ẹni tó máa dà bí rẹ mọ́.+
26 Ọlọ́run ń fún ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ àti ìdùnnú,+ àmọ́ ó ń fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní iṣẹ́ kíkó jọ àti ṣíṣà jọ kí wọ́n lè fún ẹni tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tòótọ́.+ Asán ni èyí pẹ̀lú, ìmúlẹ̀mófo* sì ni.
17 Ọlọ́run tòótọ́ fún àwọn ọ̀dọ́* mẹ́rin yìí ní ìmọ̀ àti òye nínú oríṣiríṣi ìkọ̀wé àti ọgbọ́n; ó sì fún Dáníẹ́lì ní òye láti túmọ̀ onírúurú ìran àti àlá.+
25 Nígbà náà, Jésù sọ pé: “Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, mo yìn ọ́ ní gbangba, torí pé o fi àwọn nǹkan yìí pa mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ọmọdé.+
5 Torí náà, tí ẹnikẹ́ni nínú yín ò bá ní ọgbọ́n, kó máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run,+ ó sì máa fún un,+ torí ó lawọ́ sí gbogbo èèyàn, kì í sì í pẹ̀gàn*+ tó bá ń fúnni.