Ẹ́kísódù 22:28 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 28 “O ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ òdì sí* Ọlọ́run+ tàbí kí o sọ̀rọ̀ òdì sí ìjòyè* nínú àwọn èèyàn rẹ.+ Oníwàásù 8:2-4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 2 Mo ní: “Pa àṣẹ ọba mọ́+ nítorí o ti búra níwájú Ọlọ́run.+ 3 Má ṣe yára kúrò níwájú rẹ̀.+ Má ṣe lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó burú;+ torí ohun tó bá wù ú ló lè ṣe, 4 nítorí ohun tí ọba bá sọ ni abẹ gé;+ ta ló sì lè bi í pé, ‘Kí lò ń ṣe?’” Oníwàásù 10:20 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 20 Kódà nínú èrò rẹ,* má ṣe bú* ọba,+ má sì bú olówó nínú yàrá rẹ; torí pé ẹyẹ kan* lè gbé ọ̀rọ̀* náà tàbí kí ohun tó ní ìyẹ́ tún ọ̀rọ̀ rẹ sọ.
2 Mo ní: “Pa àṣẹ ọba mọ́+ nítorí o ti búra níwájú Ọlọ́run.+ 3 Má ṣe yára kúrò níwájú rẹ̀.+ Má ṣe lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó burú;+ torí ohun tó bá wù ú ló lè ṣe, 4 nítorí ohun tí ọba bá sọ ni abẹ gé;+ ta ló sì lè bi í pé, ‘Kí lò ń ṣe?’”
20 Kódà nínú èrò rẹ,* má ṣe bú* ọba,+ má sì bú olówó nínú yàrá rẹ; torí pé ẹyẹ kan* lè gbé ọ̀rọ̀* náà tàbí kí ohun tó ní ìyẹ́ tún ọ̀rọ̀ rẹ sọ.