26 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Tú láwàní, kí o sì ṣí adé.+ Èyí ò ní rí bíi ti tẹ́lẹ̀.+ Gbé ẹni tó rẹlẹ̀ ga,+ kí o sì rẹ ẹni gíga wálẹ̀.+27 Àwókù, àwókù, ṣe ni màá sọ ọ́ di àwókù. Kò ní jẹ́ ti ẹnì kankan títí ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí i lọ́nà òfin fi máa dé,+ òun sì ni èmi yóò fún.’+
25 Wọ́n máa lé ọ kúrò láàárín àwọn èèyàn, ọ̀dọ̀ àwọn ẹranko ni wàá máa gbé, a sì máa fún ọ ní ewéko jẹ bí akọ màlúù; ìrì ọ̀run máa sẹ̀ sí ọ lára,+ ìgbà méje + sì máa kọjá lórí rẹ,+ títí o fi máa mọ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Alákòóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tó bá sì wù ú ló ń gbé e fún.+