32 Ẹni yìí máa jẹ́ ẹni ńlá,+ wọ́n á máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ,+ Jèhófà* Ọlọ́run sì máa fún un ní ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀,+33 ó máa jẹ Ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, Ìjọba rẹ̀ ò sì ní lópin.”+
5 Àmọ́ ọ̀kan lára àwọn àgbààgbà náà sọ fún mi pé: “Má sunkún mọ́. Wò ó! Kìnnìún ẹ̀yà Júdà,+ gbòǹgbò+ Dáfídì,+ ti ṣẹ́gun+ kó lè ṣí àkájọ ìwé náà àti èdìdì méje rẹ̀.”