-
2 Àwọn Ọba 22:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Àmọ́, ní ti ọba Júdà tó rán yín pé kí ẹ lọ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ẹ sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Ní ti àwọn ọ̀rọ̀ tí o gbọ́, 19 nítorí pé ọlọ́kàn tútù ni ọ́* tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀+ níwájú Jèhófà bí o ṣe gbọ́ ohun tí mo sọ pé màá ṣe sí ibí yìí àti sí àwọn tó ń gbé ibẹ̀, pé wọ́n á di ohun àríbẹ̀rù àti ẹni ègún, tí o sì fa aṣọ rẹ ya,+ tí ò ń sunkún níwájú mi, èmi náà ti gbọ́ ohun tí o sọ, ni Jèhófà wí.
-
-
Lúùkù 15:22-24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Àmọ́ bàbá náà sọ fún àwọn ẹrú rẹ̀ pé, ‘Ó yá! ẹ mú aṣọ wá, aṣọ tó dáa jù, kí ẹ wọ̀ ọ́ fún un, kí ẹ fi òrùka sí i lọ́wọ́, kí ẹ sì wọ bàtà sí i lẹ́sẹ̀. 23 Kí ẹ tún mú ọmọ màlúù tó sanra wá, kí ẹ dúńbú rẹ̀, ká jọ jẹun, ká sì yọ̀, 24 torí pé ọmọ mi yìí kú, àmọ́ ó ti pa dà wà láàyè;+ ó sọ nù, a sì rí i.’ Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn ara wọn.
-
-
Lúùkù 18:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Àmọ́ agbowó orí náà dúró ní ọ̀ọ́kán, kò fẹ́ gbé ojú rẹ̀ sókè láti wo ọ̀run pàápàá, ṣùgbọ́n ó ń lu àyà rẹ̀ ṣáá, ó ń sọ pé, ‘Ọlọ́run, ṣàánú mi,* ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.’+ 14 Mo sọ fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀ kalẹ̀ lọ sílé rẹ̀, a sì kà á sí olódodo ju Farisí yẹn lọ.+ Torí pé gbogbo ẹni tó bá gbé ara rẹ̀ ga, a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, a máa gbé e ga.”+
-