7 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ nínú ìjẹ́mímọ́ rẹ̀ pé:
“Màá yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun, màá fi Ṣékémù+ ṣe ogún fún àwọn èèyàn mi,
Màá sì díwọ̀n Àfonífojì Súkótù+ fún ẹni tí mo bá fẹ́.
8 Gílíádì+ jẹ́ tèmi, bí Mánásè ṣe jẹ́ tèmi,
Éfúrémù sì ni akoto orí mi;+
Júdà ni ọ̀pá àṣẹ mi.+
9 Móábù ni bàsíà tí mo fi ń wẹ ẹsẹ̀.+
Orí Édómù ni màá ju bàtà mi sí.+
Màá kígbe ìṣẹ́gun lórí Filísíà.”+