6 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ nínú ìjẹ́mímọ́ rẹ̀ pé:
“Màá yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun, màá fi Ṣékémù ṣe ogún fún àwọn èèyàn mi,+
Màá sì díwọ̀n Àfonífojì Súkótù fún ẹni tí mo bá fẹ́.+
7 Gílíádì jẹ́ tèmi, bí Mánásè ṣe jẹ́ tèmi,+
Éfúrémù sì ni akoto orí mi;
Júdà ni ọ̀pá àṣẹ mi.+
8 Móábù ni bàsíà tí mo fi ń wẹ ẹsẹ̀.+
Orí Édómù ni màá ju bàtà mi sí.+
Màá kígbe ìṣẹ́gun lórí Filísíà.”+