-
Sáàmù 119:139Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
139 Ìtara mi fún ọ gbà mí lọ́kàn,+
Nítorí àwọn ọ̀tá mi ti gbàgbé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ.
-
-
Máàkù 11:15-17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Wọ́n wá dé Jerúsálẹ́mù. Ó wọnú tẹ́ńpìlì níbẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn tó ń tajà àti àwọn tó ń rajà nínú tẹ́ńpìlì síta, ó sì dojú tábìlì àwọn tó ń pààrọ̀ owó dé àti bẹ́ǹṣì àwọn tó ń ta àdàbà,+ 16 kò sì jẹ́ kí ẹnì kankan gbé ohun èlò gba tẹ́ńpìlì kọjá. 17 Ó ń kọ́ wọn, ó sì ń sọ fún wọn pé: “Ṣebí a ti kọ ọ́ pé, ‘A ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè’?+ Àmọ́ ẹ ti sọ ọ́ di ihò àwọn olè.”+
-
-
Jòhánù 2:13-17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Ìrékọjá+ àwọn Júù ti sún mọ́lé, Jésù sì gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù. 14 Ó rí àwọn tó ń ta màlúù, àgùntàn àti àdàbà+ nínú tẹ́ńpìlì, ó sì rí àwọn tó ń pààrọ̀ owó lórí ìjókòó wọn. 15 Torí náà, ó fi okùn ṣe ẹgba, ó sì lé gbogbo àwọn tó ní àgùntàn àti màlúù jáde nínú tẹ́ńpìlì, ó da ẹyọ owó àwọn tó ń pààrọ̀ owó sílẹ̀, ó sì dojú àwọn tábìlì wọn dé.+ 16 Ó sọ fún àwọn tó ń ta àdàbà pé: “Ẹ kó àwọn nǹkan yìí kúrò níbí! Ẹ yéé sọ ilé Baba mi di ilé ìtajà!”*+ 17 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé a ti kọ ọ́ pé: “Ìtara ilé rẹ máa gbà mí lọ́kàn.”+
-