16 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Wò ó! O ò ní pẹ́ kú,* àwọn èèyàn yìí á sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọlọ́run àjèjì tó yí wọn ká ní ilẹ̀ tí wọ́n ń lọ ṣe àgbèrè ẹ̀sìn.+ Wọ́n á pa mí tì,+ wọ́n á sì da májẹ̀mú mi tí mo bá wọn dá.+
20Ọkùnrin oníwàhálà kan wà tó ń jẹ́ Ṣébà,+ ọmọ Bíkíráì láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni. Ó fun ìwo,+ ó sì sọ pé: “Àwa kò ní ìpín kankan nínú Dáfídì, a kò sì ní ogún kankan nínú ọmọ Jésè.+ Ìwọ Ísírẹ́lì! Kí kálukú pa dà sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run* rẹ̀.”+
26 “Àmọ́, wọ́n ya aláìgbọràn, wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọ,+ wọ́n sì kẹ̀yìn sí Òfin rẹ.* Wọ́n pa àwọn wòlíì rẹ tó kìlọ̀ fún wọn láti mú wọn pa dà sọ́dọ̀ rẹ, wọ́n sì hu ìwà àìlọ́wọ̀ tó bùáyà.+