Sáàmù 34:14 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 14 Jáwọ́ nínú ohun búburú, kí o sì máa ṣe rere;+Máa wá àlàáfíà, kí o sì máa lépa rẹ̀.+ Sáàmù 101:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Mi ò ní gbé ohun tí kò ní láárí* sí iwájú mi. Mo kórìíra iṣẹ́ àwọn tó ń yà kúrò nínú ohun tí ó tọ́;+Mi ò ní bá wọn da nǹkan kan pọ̀.* Sáàmù 119:104 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 104 Àwọn àṣẹ rẹ ló mú kí n máa fòye hùwà.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi kórìíra gbogbo ọ̀nà èké.+ Róòmù 12:9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yín wà láìsí ẹ̀tàn.*+ Ẹ kórìíra ohun búburú;+ ẹ rọ̀ mọ́ ohun rere. Hébérù 1:9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 O nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà tí kò bófin mu. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ, fi fòróró ayọ̀ yàn ọ́+ ju àwọn ojúgbà rẹ.”+
3 Mi ò ní gbé ohun tí kò ní láárí* sí iwájú mi. Mo kórìíra iṣẹ́ àwọn tó ń yà kúrò nínú ohun tí ó tọ́;+Mi ò ní bá wọn da nǹkan kan pọ̀.*
9 O nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà tí kò bófin mu. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ, fi fòróró ayọ̀ yàn ọ́+ ju àwọn ojúgbà rẹ.”+