17 Àmọ́, ọgbọ́n tó wá láti òkè á kọ́kọ́ jẹ́ mímọ́,+ lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà,+ ó ń fòye báni lò,+ ó ṣe tán láti ṣègbọràn, ó máa ń ṣàánú gan-an, ó sì ń so èso rere,+ kì í ṣe ojúsàájú,+ kì í sì í ṣe àgàbàgebè.+
22 Ní báyìí tí ẹ ti fi ìgbọràn yín sí òtítọ́ wẹ ara yín* mọ́, tí èyí sì mú kí ẹ ní ìfẹ́ ará láìsí ẹ̀tàn,+ kí ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí ara yín látọkàn wá.+