31 Jèhófà wá mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ wá lójijì, ó gbá àwọn ẹyẹ àparò wá láti òkun, ó sì mú kí wọ́n já bọ́ yí ibùdó+ náà ká, nǹkan bí ìrìn àjò ọjọ́ kan lápá ibí àti ìrìn àjò ọjọ́ kan lápá ọ̀hún, yí ibùdó náà ká, ìpele wọn sì ga tó nǹkan bí ìgbọ̀nwọ́ méjì sílẹ̀.